عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«مَا مِنْ يَوْمٍ يُصْبِحُ العِبَادُ فِيهِ إِلَّا مَلَكَانِ يَنْزِلاَنِ، فَيَقُولُ أَحَدُهُمَا: اللَّهُمَّ أَعْطِ مُنْفِقًا خَلَفًا، وَيَقُولُ الآخَرُ: اللَّهُمَّ أَعْطِ مُمْسِكًا تَلَفًا».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 1442]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayrah, kí Ọlọhun bá wa yọnu si, o sọ pe: dájúdájú Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba - sọ bayi pe:
Kosi ọjọ kan ti awọn ẹrusin yóò jí ní àárọ̀ ayaafi kí ó jasipe awọn malaika (iranṣẹ Ọlọhun) meji yoo sọkalẹ sí ọdọ ẹnikọọkan, ọkan ninu awọn mejeeji yóò máa ṣọ pe: "Irẹ Ọlọhun dakun bá mi ṣe irọpo owo fún ẹni tí n nawo rẹ, bẹẹ ni ikeji yóò máa ṣọ pe: "Bami fi iparun ati ibajẹ sinu owo ẹni tí ó kọ̀ lati ma na owo, tí ó wowọ́ mọ́n owo kankan.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1442]
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti fún wa ni iro pe kosi ọjọ kan ti oorun yọ ayaafi ki awọn malaika meji sọkale ti wọn yóò sì máa pe Ọlọhun, ọkan ninu wọn yóò sọ pé:
"Ọlọhun bami fi ọpọ rọpo fún ẹni tí n nawo rẹ ni itẹle aṣẹ Ọlọhun, ati fún awọn ẹbi (ọmọ, iyawo, baba, ati iya....) ati igbalejo, ati sí bi awọn iṣẹ àṣegbọrẹ, bami fi èyí to lóore pupọ ju èyí to na lọ rọpo fun un, ki o si ṣe ibukún Rẹ fun".
Ẹnikeji awọn malaika náà yóò máa sọ pe: "Ọlọhun bá mi ṣe iparẹ ati ibajẹ sí owo ẹni tí ó kọ̀ lati maa na owo rẹ, bá mi ko iparun ba owo tabi dukia tí ó kọ̀ lati na fún awọn ti o lẹtọọ sí i".