+ -

عَنْ خُرَيْمِ بْنِ فَاتِكٍ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«الْأَعْمَالُ سِتَّةٌ، وَالنَّاسُ أَرْبَعَةٌ، فَمُوجِبَتَانِ، وَمِثْلٌ بِمِثْلٍ، وَحَسَنَةٌ بِعَشْرِ أَمْثَالِهَا، وَحَسَنَةٌ بِسَبْعِ مِائَةٍ، فَأَمَّا الْمُوجِبَتَانِ: فَمَنْ مَاتَ لَا يُشْرِكُ بِاللهِ شَيْئًا دَخَلَ الْجَنَّةَ، وَمَنْ مَاتَ يُشْرِكُ بِاللهِ شَيْئًا دَخَلَ النَّارَ، وَأَمَّا مِثْلٌ بِمِثْلٍ: فَمَنْ هَمَّ بِحَسَنَةٍ حَتَّى يَشْعُرَهَا قَلْبُهُ، وَيَعْلَمَهَا اللهُ مِنْهُ كُتِبَتْ لَهُ حَسَنَةً، وَمَنْ عَمِلَ سَيِّئَةً، كُتِبَتْ عَلَيْهِ سَيِّئَةً، وَمَنْ عَمِلَ حَسَنَةً فَبِعَشْرِ أَمْثَالِهَا، وَمَنْ أَنْفَقَ نَفَقَةً فِي سَبِيلِ اللهِ فَحَسَنَةٌ بِسَبْعِ مِائَةٍ، وَأَمَّا النَّاسُ، فَمُوَسَّعٌ عَلَيْهِ فِي الدُّنْيَا مَقْتُورٌ عَلَيْهِ فِي الْآخِرَةِ، وَمَقْتُورٌ عَلَيْهِ فِي الدُّنْيَا مُوَسَّعٌ عَلَيْهِ فِي الْآخِرَةِ، وَمَقْتُورٌ عَلَيْهِ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ، وَمُوَسَّعٌ عَلَيْهِ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ».

[حسن] - [رواه أحمد] - [مسند أحمد: 18900]
المزيــد ...

Lati ọdọ Khuraim ọmọ Faatik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Mẹ́fà ni àwọn iṣẹ́, mẹrin si ni àwọn èèyàn, méjì maa n sọ nǹkan di dandan, ati èyí ti o ṣe pe déédéé iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan rẹ, ati eyi ti o ṣe pe iṣẹ rere kan pẹlu ẹsan mẹ́wàá ni, ati eyi ti o ṣe pe iṣẹ rere kan pẹlu ẹẹdẹgbẹrin ẹsan ni, ṣe ẹ wa ri méjì tii sọ nǹkan di dandan: Ẹni tí ó bá kú, ti ko si da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, yoo wọ alujanna, ẹni tí ó bá kú ti o si da nnkan pọ mọ Ọlọhun, yoo wọ ina, ṣe ẹ wa ri èyí ti o ṣe pe déédéé iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan rẹ: Ẹni ti o ba gbèrò dáadáa títí ti ọkàn rẹ fi mọ ọn lára, ti Ọlọhun si mọ ọn lati ọdọ rẹ, wọn maa kọ ọ silẹ fun un ni ẹsan kan, ẹni tí ó bá ṣe aburu kan, wọn maa kọ ọ silẹ fun un ni aburu kan, ẹni tí o ba ṣe dáadáa kan, o maa gba ẹsan mẹ́wàá irú rẹ, ẹni tí ó bá na owó si oju-ọna Ọlọhun, dáadáa kan maa wa pẹlu ẹsan ẹẹdẹgbẹrin, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn, o n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun maa gbòòrò arisiki rẹ ni ayé ṣùgbọ́n ti o maa ri ifunpinpin ni alukiyaamọ, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun ko nii gbòòrò arisiki fun ni ayé, ṣùgbọ́n o maa ri igbalaaye ni alukiyaamọ, o tun bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun ko nii gbòòrò arisiki fun ni ayé ati alukiyaamọ, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun maa gbòòrò arisiki rẹ ni ayé ati alukiyaamọ”.

[O daa] - [Ahmad ni o gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 18900]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe iran mẹfa ni àwọn iṣẹ, iran mẹ́rin si ni àwọn èèyàn. Àwọn iṣẹ́ mẹfẹẹfa naa ni:
Akọkọ: Ẹni tí ó bá ku ti ko da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, alujanna di dandan fun un.
Ẹlẹẹkeji: Ẹni tí ó bá kú ti o si da nǹkan pọ mọ Ọlọhun, ina di dandan fún un, yoo si ṣe gbere ninu ẹ.
Àwọn mejeeji ni nnkan meji ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan.
Ẹlẹẹkẹta: Daadaa ti a gbero, ẹni tí ó bá gbero lati ṣe dáadáa pẹ̀lú aniyan òdodo titi ti ọkan rẹ fi maa mọ ọn lara ti Ọlọhun naa si mọ àníyàn yii lati ọdọ rẹ, ki àlámọ̀rí kan waa sẹlẹ si i lẹ́yìn naa, ti ko waa ni ikapa lati ṣe daadaa yii, wọn maa kọ ẹsan ti o pe fun un.
Ikẹrin: Aburu ti a ṣe, ẹni ti o ba ṣe aburu kan wọn maa kọ aburu kan fun un.
Àwọn mejeeji ni: Iru kan pẹlu iru kan laini adipele.
Ikarun-un: Daadaa ti o maa jẹ pẹlu daadaa mẹwaa iru rẹ, oun ni ẹni ti o gbero daadaa ti o si ṣe é; wọn maa kọ daadaa mẹwaa fun un.
Ikẹfa: Daadaa ti o maa jẹ pẹlu ẹẹdẹgbẹrin ẹsan, oun ni ẹni ti o ba na owó kan si oju ọna Ọlọhun, wọn maa kọ daadaa yii fun un pẹlu ẹẹdẹgbẹrin daadaa, eleyii wa ninu ọlá Rẹ- ìbùkún ni fun Un ti ọla Rẹ ga- ati ọrẹ Rẹ lori awọn ẹru Rẹ.
Ṣugbọn àwọn iran awọn eniyan mẹrẹẹrin ni:
Akọkọ: Ẹni ti wọn maa gba laaye ni aye ninu arisiki, wọn maa dẹ ẹ lara nibẹ pẹlu nnkan ti o ba fẹ, sugbọn wọn maa fun pinpin mọ ọn ni ọrun ti ìkángun rẹ si maa jẹ ina, oun ni alaigbagbọ ọlọrọ.
Ikeji: Ẹni ti wọn maa fun pinpin mọ ọn ni aye ninu arisiki, sugbọn wọn maa gba a laaye ni ọrun, ti ìkángun rẹ si maa jẹ alujanna, oun ni olugbagbọ alaini.
Ikẹta: Ẹni ti wọn maa fun pinpin mọ ọn ni aye ati ọrun, oun ni alaigbagbọ alaini.
Ikẹrin: Ẹni ti wọn maa gba a laaye ni aye ati ọrun, oun ni olugbagbọ ọlọrọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titobi ọla Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori awọn ẹru ati ṣíṣe adipele Rẹ fun awọn daadaa.
  2. Ìṣe deedee Ọlọhun ati ọrẹ Rẹ, nigba ti o ba wa lò nibi aburu pẹlu déédéé ti ẹsan aburu si jẹ ẹyọkan.
  3. Titobi dida nnkan pọ mọ Ọlọhun, àìní wọ alujanna sì n bẹ nibẹ.
  4. Alaye ọla nina owo si oju ọna Ọlọhun.
  5. Adipele ẹsan nina owo si oju ọna Ọlọhun bẹrẹ lati adipele ẹẹdẹgbẹrin; nitori pe o maa ṣe iranlọwọ lati mu ọrọ Ọlọhun ga.
  6. Alaye awọn iran awọn eniyan ati yiyatọ wọn.
  7. Wọn maa gba olugbagbọ laaye ni aye ati alaigbagbọ, ṣùgbọ́n wọn ko nii gba ẹnikẹni laaye ni ọrun afi olugbagbọ.