عَنْ أَنَسِ بْنِ مَالِكٍ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِنَّ اللهَ لَا يَظْلِمُ مُؤْمِنًا حَسَنَةً، يُعْطَى بِهَا فِي الدُّنْيَا وَيُجْزَى بِهَا فِي الْآخِرَةِ، وَأَمَّا الْكَافِرُ فَيُطْعَمُ بِحَسَنَاتِ مَا عَمِلَ بِهَا لِلَّهِ فِي الدُّنْيَا، حَتَّى إِذَا أَفْضَى إِلَى الْآخِرَةِ، لَمْ تَكُنْ لَهُ حَسَنَةٌ يُجْزَى بِهَا».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2808]
المزيــد ...
Lati ọdọ Anas ọmọ Malik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dajudaju Ọlọhun ko nii ṣe abosi olugbagbọ kan ni ti daadaa ti o ba ṣe, wọn yoo fun un ni ẹsan rẹ ni aye, wọn si tun maa san an ni ẹsan pẹlu rẹ ni ọrun, sugbọn alaigbagbọ wọn maa fun un ni oúnjẹ jẹ pẹlu awọn daadaa nnkan ti o ba ṣe ni iṣẹ́ nitori Ọlọhun ni aye, ti o ba ti wa de ọrun, daadaa kan ko nii maa jẹ tirẹ ti wọn maa san an lẹsan pẹlu rẹ”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2808]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé titobi ọla Ọlọhun lori awọn olugbagbọ, ati ṣíṣe deedee Rẹ pẹlu awọn alaigbagbọ. Ṣugbọn olugbagbọ, ẹsan daadaa ti o ba ṣe ko nii dínkù; bi ko ṣe pe wọn maa fun un ni dáadáa pẹlu rẹ ni aye lori itẹle rẹ, pẹlu nnkan ti wọn maa fi pamọ fun un ninu ẹsan ni ọrun; wọn si le tọju gbogbo ẹsan naa fun un ni ọrun. Ṣugbọn alaigbagbọ, Ọlọhun maa fun un ni ẹsan nnkan ti o ba ṣe ninu awọn daadaa pẹlu awọn daadaa aye, ti o ba ti wa de ọrun, ko nii si ẹsan kan ti wọn yoo san an lẹsan rẹ; nitori pe iṣẹ rere ti yoo ṣeni ni anfaani ni aye ati ọrun dandan ni ki ẹni ti o ṣe e jẹ olugbagbọ.