عَنْ عُبَادَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«مَنْ شَهِدَ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، وَأَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ، وَأَنَّ عِيسَى عَبْدُ اللهِ وَرَسُولُهُ وَكَلِمَتُهُ أَلْقَاهَا إِلَى مَرْيَمَ وَرُوحٌ مِنْهُ، وَالْجَنَّةُ حَقٌّ، وَالنَّارُ حَقٌّ، أَدْخَلَهُ اللهُ الْجَنَّةَ عَلَى مَا كَانَ مِنَ الْعَمَلِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3435]
المزيــد ...
Lati ọdọ ‘Ubadah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Ẹni ti o ba jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu ni ọkan soso ti ko si akẹgbẹ fun Un, ati pe dajudaju Muhammad ẹrusin Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe Isa ẹrusin Ọlọhun ni ojiṣẹ Rẹ si tun ni ati pe ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni, ati pe al-jannah ododo ni, ina ododo ni, Ọlọhun a mu u wọ al-jannah lori èyíkéyìí iṣẹ ti o ba wa lori rẹ»
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3435]
Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fun wa ni iro pe dajudaju ẹni ti o ba sọ gbolohun mimu Ọlọhun lọkan (Laa illaha illā Allāhu) l'ẹni ti o mọ itumọ rẹ ti o si n ṣiṣẹ tọ nkan ti o n pepe si, ti o si tun jẹrii si jijẹ ẹrusin Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati ijẹ ojiṣẹ rẹ, tí o si tun fi jíjẹ́ ẹrusin ati jijẹ ojiṣẹ Isa rinlẹ, Àti pé dajudaju Ọlọhun da a pẹlu gbolohun Rẹ pe "kun" (jẹ bẹ́ẹ̀) ti o si jẹ bẹ́ẹ̀, ati pe o jẹ ẹmi kan ninu awọn ẹmi ti Ọlọhun da, ti o si tun fọ iya rẹ mọ kuro nibi nkan ti awọn Yahudi fi ti si i lọdọ, Ti o si tun ni igbagbọ pe dajudaju al-jannah ododo ni, ati pe ina ododo ni, lẹniti o ni adisọkan bíbẹ mejeeji, ati pe dajudaju awọn mejeeji idẹra Ọlọhun ati ijiya Rẹ ni, Ti o si ku lori iyẹn; nitori naa ibudesi rẹ ni Aljannah koda ki o jẹ alaseeto nibi itẹle, ti awọn ẹṣẹ si n bẹ fun un.