+ -

عَنْ سُفْيان بنِ عَبْدِ اللهِ الثَّقَفِيّ رضي الله عنه قال:
قُلْتُ: يَا رَسُولَ اللهِ، قُلْ لِي فِي الْإِسْلَامِ قَوْلًا لَا أَسْأَلُ عَنْهُ أَحَدًا غَيْرَكَ، قَالَ: «قُلْ: آمَنْتُ بِاللهِ، ثُمَّ اسْتَقِمْ».

[صحيح] - [رواه مسلم وأحمد]
المزيــد ...

Lati ọdọ Sufyan ọmọ Abdullahi Ath-Thaqoofiy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee".

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Saabe Sufyan ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere lati kọ oun ni ọrọ kan ti o ko awọn ìtumọ̀ Isilaamu sinu, ti oun maa dirọ mọ ọn, ti oun ko si nii bi ẹni ti o yàtọ̀ si i leere nipa rẹ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: sọ pe Mo mu Ọlọhun lọkan, mo si gbagbọ pe Oluwa mi ni ati Ọlọhun mi ati Aṣẹ̀dá mi ati Ẹni ti maa maa jọsin fun lododo ti ko si orogun fun Un, Lẹyin naa, yoo tẹ fun itẹle Ọlọhun pẹlu ṣíṣe awọn ọran-anyan Ọlọhun ati gbigbe awọn eewọ Ọlọhun ju silẹ ti yoo si maa tẹsiwaju lori rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ipilẹ ẹsin ni nini igbagbọ ninu Ọlọhun pẹlu ijẹ Oluwa Rẹ ati ijẹ Ọlọhun Rẹ ati awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.
  2. Pataki iduro ṣinṣin lẹyin igbagbọ, ati itẹsiwaju nibi ijọsin, ati fifi ẹsẹ rinlẹ lori ìyẹn.
  3. Igbagbọ jẹ majẹmu itẹwọgba awọn iṣẹ.
  4. Nini igbagbọ ninu Ọlọhun, ko nnkan ti adisọkan rẹ jẹ dandan sinu ninu awọn adisọkan igbagbọ ati awọn ipilẹ rẹ, ati nnkan ti o tẹle ìyẹn ninu awọn iṣẹ ọkan, ati itẹle ati gbigba fun Ọlọhun ni kọkọ ati ni gbangba.
  5. Iduro ṣinṣin ni ki èèyàn má kúrò ni oju ọna, pẹlu ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn nnkan ti a kọ ju silẹ.