+ -

عَنِ ابْنِ عَبَّاسٍ رضي الله عنهما قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ أَنْ تُؤْتَى رُخَصُهُ، كَمَا يُحِبُّ أَنْ تُؤْتَى عَزَائِمُهُ».

[صحيح] - [رواه ابن حبان] - [صحيح ابن حبان: 354]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”.

[O ni alaafia] - [Ibnu Hibbaan ni o gba a wa] - [Sọhiihu ti Ibnu Hibbaan - 354]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju Ọlọhun maa n nífẹ̀ẹ́ sí mímú awọn ofin idẹkun Rẹ ti O ṣe wọn lofin wa, ninu awọn nnkan ti O ṣe wọn ni fifuyẹ nibi awọn idajọ ati ijọsin, ati ṣíṣe irọrun nibẹ fun awọn ẹni ti a la iwọ Ọlọhun bọ lọrun fun idi kan- gẹgẹ bii dindin irun ku ati dida a pọ ni ori irin ajo-, Gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ si mimu awọn ofin ti wọn jẹ dandan wa, ninu awọn alamọri ti wọn jẹ dandan; nitori pe aṣẹ Ọlọhun nibi awọn ìdẹkùn ati awọn nnkan ti wọn jẹ dandan jẹ ọ̀kan.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ikẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori awọn ẹru Rẹ, ati pe Ọlọhun- mimọ ni fun Un- nífẹ̀ẹ́ si mimu nnkan ti o ba ṣe lofin wa ninu awọn idẹkun.
  2. Pipe ofin sharia yii, ati gbigbe ìdààmú rẹ kuro fun Musulumi.