عَنْ حَكِيمِ بْنِ حِزَامٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ، قَالَ:
قُلْتُ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، أَرَأَيْتَ أَشْيَاءَ كُنْتُ أَتَحَنَّثُ بِهَا فِي الجَاهِلِيَّةِ مِنْ صَدَقَةٍ أَوْ عَتَاقَةٍ، وَصِلَةِ رَحِمٍ، فَهَلْ فِيهَا مِنْ أَجْرٍ؟ فَقَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «أَسْلَمْتَ عَلَى مَا سَلَفَ مِنْ خَيْرٍ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 1436]
المزيــد ...
Lati ọdọ Hakeem ọmọ Hizaam- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe:
Mo sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, fun mi ni iro nipa nnkan ti mo maa n se wọn ni asiko aimọkan bii saara ṣíṣe ati bibọkun kúrò lọrun ẹru ati dida ibi pọ, njẹ ẹsan wa nibẹ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “O gba Isilaamu lori nnkan ti o ṣáájú ninu daadaa”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1436]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe alaigbagbọ ti o ba gba Isilaamu wọn maa san an lẹsan lori nnkan ti o n ṣe ni asiko aimọkan ṣíwájú gbigba Isilaamu rẹ ninu awọn iṣẹ oloore bii saara ṣíṣe ati bibọkun kúrò lọrun ẹru tabi siso ibi papọ.