عَنِ ابْنِ عُمَرَ رضي الله عنهما عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، قَالَ:
«مَثَلُ الْمُنَافِقِ، كَمَثَلِ الشَّاةِ الْعَائِرَةِ بَيْنَ الْغَنَمَيْنِ تَعِيرُ إِلَى هَذِهِ مَرَّةً وَإِلَى هَذِهِ مَرَّةً».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2784]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe:
“Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2784]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iṣesi ṣọbẹ-ṣelu pe o da gẹgẹ bii aguntan ti o n ṣe iyemeji ti ko mọ eyi ti o maa tẹle ninu agbo aguntan méjèèjì, O maa lọ ba agbo yii nigba mii, a tun lọ ba omiran nigba mii, Wọn wa ninu idaamu-daabo laaarin igbagbọ ati aigbagbọ, wọn ko si pẹlu awọn olugbagbọ ni ti gbangba ati ni kọkọ, wọn ko si tun si pẹlu awọn alaigbagbọ ni gbangba ati ni kọkọ, bi ko ṣe pe gbangba wọn wa pẹlu awọn olugbagbọ, ti kọkọ wọn si wa nibi iyemeji ati aisi lojukan, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii.