عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بْنِ عَمْرِو بْنِ الْعَاصِ رضي الله عنهما قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِنَّ الْإِيمَانَ لَيَخْلَقُ فِي جَوْفِ أَحَدِكُمْ كَمَا يَخْلَقُ الثَّوْبُ الْخَلِقُ، فَاسْأَلُوا اللَّهَ أَنْ يُجَدِّدَ الْإِيمَانَ فِي قُلُوبِكُمْ».
[صحيح] - [رواه الحاكم والطبراني] - [المستدرك على الصحيحين: 5]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”.
[O ni alaafia] - [Al-Haakim ati At-Tọbarọọniy ni wọ́n gba a wa] - [Al-Mustadrak alaa Sohiihaen - 5]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju igbagbọ maa n gbo ni ọkan Musulumi o si maa n lẹ gẹgẹ bi aṣọ tuntun ti o maa n gbo ti wọn ba ti lo o fun ìgbà pípẹ́; Ati pe ìyẹn maa n ṣẹlẹ̀ pẹlu okunfa adinku nibi ijọsin, tabi dida awọn ẹṣẹ ati titẹri sinu awọn adun. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọ́ wa sọna lati maa pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lati maa sọ igbagbọ wa di tuntun, pẹlu ṣíṣe awọn ọran-anyan ati pipọ ni iranti ati wiwa aforijin.