+ -

عَنْ أَنَسٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ، قَالَ: لَأُحَدِّثَنَّكُمْ حَدِيثًا سَمِعْتُهُ مِنْ رَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لاَ يُحَدِّثُكُمْ بِهِ أَحَدٌ غَيْرِي: سَمِعْتُ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«إِنَّ مِنْ أَشْرَاطِ السَّاعَةِ أَنْ يُرْفَعَ العِلْمُ، وَيَكْثُرَ الجَهْلُ، وَيَكْثُرَ الزِّنَا، وَيَكْثُرَ شُرْبُ الخَمْرِ، وَيَقِلَّ الرِّجَالُ، وَيَكْثُرَ النِّسَاءُ حَتَّى يَكُونَ لِخَمْسِينَ امْرَأَةً القَيِّمُ الوَاحِدُ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo maa sọ hadiisi kan fun yin ti mo gbọ́ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko si ẹni ti o le sọ ọ fun yin yatọ sí mi: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
"c2">“Dajudaju ninu awọn ami ọjọ igbende ni ki wọn ka imọ kúrò nílẹ̀, ki aimọkan si pọ, ki ṣina si pọ, ti ọti mimu si maa pọ, ti onka awọn ọkunrin si maa kere, ti onka awọn obinrin si maa pọ titi ti o fi maa jẹ pe ọkùnrin kan ni yoo maa bẹ fun aadọta obinrin”.

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ninu awọn ami sisunmọ asiko igbende ni ki wọn ka imọ sharia kuro nilẹ, ati pe ìyẹn maa ri bẹẹ pẹlu iku awọn onimimọ, Ati pe esi ìyẹn ni pe ki aimọkan pọ ki o si fọnka, ki ṣina ati iwa aburu maa fọnka, ati ki mimu ọti pọ̀, onka awọn ọkunrin sì maa kere, ti onka obinrin si maa pọ titi ti o fi maa di pe ọkùnrin kan ni yoo maa bẹ fun aadọta obinrin ti yoo maa mójú tó awọn alamọri wọn ati awọn anfaani wọn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣalaye díẹ̀ ninu awọn ami ọjọ igbende.
  2. Imọ asiko igbende wa ninu awọn alamọri kọ̀kọ̀ ti o ṣe pe Ọlọhun nìkan ni Ó mọ̀ ọ́n.
  3. Ṣisẹnilojukokoro lori wiwa imọ sharia ṣíwájú pipadanu rẹ.