عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لاَ تَقُومُ السَّاعَةُ حَتَّى يَمُرَّ الرَّجُلُ بِقَبْرِ الرَّجُلِ فَيَقُولُ: يَا لَيْتَنِي مَكَانَهُ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 7115]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
"Ọjọ igbedide ko nii to titi ti arakunrin o fi maa kọja nibi saare arakunrin, o maa sọ pé: Mii ba si wa ni ipo rẹ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 7115]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ọjọ igbende ko nii to titi ti arakunrin maa fi kọja nibi saare ti yoo si maa gbero lati jẹ oku dipo rẹ, idi ni ibẹru rẹ lori ara rẹ nibi lilọ ẹsin rẹ pẹlu ibori ibajẹ ati awọn onibajẹ, ati hihan awọn fitina ati awọn ẹṣẹ ati awọn ibajẹ.