+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ عَنْ رَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لاَ تَقُومُ السَّاعَةُ حَتَّى تُقَاتِلُوا اليَهُودَ، حَتَّى يَقُولَ الحَجَرُ وَرَاءَهُ اليَهُودِيُّ: يَا مُسْلِمُ، هَذَا يَهُودِيٌّ وَرَائِي فَاقْتُلْهُ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"c2">“Ọjọ igbende ko nii to titi ẹ fi maa ba awọn Juu ja, titi okuta ti Juu wa lẹyin rẹ fi maa sọ pé: Irẹ Musulumi, eleyii ni Juu lẹyin mi, pa a”.

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ọjọ igbende ko lee to titi awọn Musulumi ati Juu fi maa ba ara wọn ja, Titi Juu fi maa sá lọ si ẹyin okuta lati fi ara pamọ fun Musulumi; Ọlọhun maa fun okuta naa ni ọrọ sọ, yoo si pe Musulumi: Pe dajudaju Juu kan wa lẹyin rẹ titi yoo fi wa pa a.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ifunni ni iro Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa díẹ̀ ninu imọ kọ̀kọ̀ ati ọjọ iwaju, ní ìbámu si nnkan ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fun un rí, o si maa ṣẹlẹ̀, dandan ni.
  2. Gbigbe ogun awọn Musulumi ti Juu ni igbẹyin aye, ati pe ìyẹn wa ninu awọn ami ọjọ igbende.
  3. Ṣiṣẹku ẹsin Isilaamu titi di ọjọ igbende, ati bibori ti o maa borí gbogbo ẹsin pata.
  4. Aranṣe Ọlọhun fun awọn Musulumi lori ọta wọn, ati pe ninu ìyẹn ni jijẹ ki okuta sọrọ ni igbẹyin aye.