عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«وَالَّذِي نَفْسِي بِيَدِهِ، لَيُوشِكَنَّ أَنْ يَنْزِلَ فِيكُمْ ابْنُ مَرْيَمَ حَكَمًا مُقْسِطًا، فَيَكْسِرَ الصَّلِيبَ، وَيَقْتُلَ الخِنْزِيرَ، وَيَضَعَ الجِزْيَةَ، وَيَفِيضَ المَالُ حَتَّى لاَ يَقْبَلَهُ أَحَدٌ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2222]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2222]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n bura lori sisunmọ sisọkalẹ Isa ọmọ Maryam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- lati maa ṣe idajọ laaarin awọn eniyan pẹlu deedee pẹlu Sharia ti Muhammad, Ati pe o maa pada run agbelebuu ti awọn Nasara n gbe tobi, Atipe Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- maa pa ẹlẹ́dẹ̀, Ati pe Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, o si maa jẹ ki gbogbo èèyàn wọnú Isilaamu. Ati pe dajudaju owo maa pada maa da ti ẹni kankan ko nii gba a; ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ fun pipọ rẹ, ati rirọrọ gbogbo ẹni kọọkan pẹlu nnkan ti o n bẹ ni ọwọ rẹ mejeeji, ati sisọkalẹ alubarika ati itẹle-ara-wọn awọn oore.