عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنْ رَسُولِ اللهِ صلى الله عليه وسلم أنه قال:
«وَالَّذِي نَفْسُ مُحَمَّدٍ بِيَدِهِ لَا يَسْمَعُ بِي أَحَدٌ مِنْ هَذِهِ الْأُمَّةِ يَهُودِيٌّ وَلَا نَصْرَانِيٌّ، ثُمَّ يَمُوتُ وَلَمْ يُؤْمِنْ بِالَّذِي أُرْسِلْتُ بِهِ إِلَّا كَانَ مِنْ أَصْحَابِ النَّارِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 153]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 153]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n bura pẹlu Ọlọhun pe ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa oun ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara tabi ẹni ti o yatọ si awọn mejeeji, ti ipepe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- de etiigbọ rẹ, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ ninu rẹ afi ki o wa ninu awọn ara ina ti o maa ṣe gbere nibẹ lailai.