عَنْ ثَوْبَانَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«أَفْضَلُ دِينَارٍ يُنْفِقُهُ الرَّجُلُ، دِينَارٌ يُنْفِقُهُ عَلَى عِيَالِهِ، وَدِينَارٌ يُنْفِقُهُ الرَّجُلُ عَلَى دَابَّتِهِ فِي سَبِيلِ اللهِ، وَدِينَارٌ يُنْفِقُهُ عَلَى أَصْحَابِهِ فِي سَبِيلِ اللهِ» قَالَ أَبُو قِلَابَةَ: وَبَدَأَ بِالْعِيَالِ، ثُمَّ قَالَ أَبُو قِلَابَةَ: وَأَيُّ رَجُلٍ أَعْظَمُ أَجْرًا مِنْ رَجُلٍ يُنْفِقُ عَلَى عِيَالٍ صِغَارٍ، يُعِفُّهُمْ أَوْ يَنْفَعُهُمُ اللهُ بِهِ وَيُغْنِيهِمْ.
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 994]
المزيــد ...
Lati ọdọ Thaobān - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Dinar (owo) ti o lọla julọ ti ọmọniyan n na ni dinar (owo) ti o na fun awọn ara ilé rẹ, ati owo ti o na lori nkan ọ̀gùn rẹ lọ si oju-ọna Ọlọhun, ati owo ti o na lori awọn ẹmẹwa rẹ ni oju-ọna Ọlọhun» Abu Qilābah wa sọ pe: O bẹrẹ pẹlu ara ilé, lẹyin naa ni Abu Qilābah wa sọ pe: Ẹni wo ni ẹsan rẹ fi wa n tobi ju ẹni ti o n na owo lori awọn ọmọ rẹ kéékèèké, ti ko nii jẹ ki wọn maa tọrọ jẹ, tabi ti Ọlọhun o fi i ṣe wọn ni anfaani ti yio si tun rọ wọn lọrọ.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 994]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye oríṣiríṣi ọ̀nà téèyàn lè gbà náwó, ti o si tun to o ti awọn ọna inawo ba fún pọ̀ ni ibamu si bi wọn ṣe jẹ dandan le ọ l'ori si, ni o wa bẹrẹ pẹlu eyiti o pataki julọ lẹyin naa eyiti o pataki tẹle e. Ni o wa sọ pe dajudaju owo ti ẹsan rẹ pọ ju ni eyi ti musulumi na lori awọn ti inawo wọn jẹ dandan fun un; bii iyawo ati ọmọ, Lẹyin naa ni inawo lori nkan ọ̀gùn ti wọn pese kalẹ fun ijagun si oju-ọna Ọlọhun, Lẹyin naa ni inawo lori awọn ọrẹ ati alabaarin ni igba ti wọn n jagun si oju-ọna Ọlọhun.