+ -

عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بْنِ مَالِكٍ ابْنِ بُحَيْنَةَ رضي الله عنه:
أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَانَ إِذَا صَلَّى فَرَّجَ بَيْنَ يَدَيْهِ حَتَّى يَبْدُوَ بَيَاضُ إِبْطَيْهِ.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 390]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mālik ọmọ Buhayna - ki Ọlọhun yọnu si i -:
Dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba n kirun yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji titi ti abiya rẹ mejeeji o fi han.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 390]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fi ori kanlẹ yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji ni iforikanlẹ; yoo si gbe ọwọ kọọkan jina si ibi ẹgbẹ ti o wa, gẹgẹ bii iyẹ meji, titi ti awọ abiya rẹ fi maa han; Ati pe eyi n bẹ ninu jijẹ ki apá méjèèjì da bii iyẹ ati gbigbe wọn jìnà gan si ẹgbẹ rẹ mejeeji.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe iṣesi yii ni ẹtọ nibi iforikanlẹ, oun naa ni gbigbe apa mejeeji jina si ẹgbẹ rẹ mejeeji.
  2. Olukirun lẹyin imaamu ti o ṣe wipe ara o maa ni ẹni ti o wa ni ẹgbẹ rẹ latara gbigbe ọwọ jina si ara wọn; ko tọ fun un ki o ṣe e.
  3. O n bẹ nibi igbe ọwọ jina si ara wọn nibi iforikanlẹ awọn ọgbọn ati anfaani ti o pọ, ninu rẹ ni: Fifi ijafafa ati ini ìfẹ́ si irun han, ti o ba da ara le gbogbo oríkèé iforikanlẹ, gbogbo oríkèé kọọkan ni yio gba ẹtọ rẹ nibi ijọsin. Wọn tun sọ pe: Ọgbọn ti o wa nibi iyẹn ni pe o jọ itẹriba, o si de ogongo nibi fifi iwaju ati imu le ilẹ daadaa, ati pe bákannáà ki oríkèé kọọkan le da yatọ.