عن ابن عمر رضي الله عنهما عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«أحْفُوا الشَّوَارِبَ وأَعْفُوا اللِّحَى».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 259]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Ẹ ge awọn tubọmu ki ẹ si da awọn irungbọn si”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 259]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ pẹlu mimu kuro lara tubọmu ati pe wọn ko gbọdọ fi i kalẹ bi ko ṣe pe ki wọn ge kuro nibẹ, ki wọn si ge e gan.
Ni ti idakeji, o n pàṣẹ pẹlu dida irungbọn si ati fifi i kalẹ ni nnkan ti o maa pọ.