عن أَنَسَ بْنَ مَالِكٍ رضي الله عنه قال:
بينما نحن جلوس مع النبي صلى الله عليه وسلم في المسجد دخل رجل على جمل، فأناخه في المسجد ثم عقله، ثم قال لهم: أيكم محمد؟ والنبي صلى الله عليه وسلم متكئ بين ظهرانيهم، فقلنا: هذا الرجل الأبيض المتكئ. فقال له الرجل: يا ابن عبد المطلب فقال له النبي صلى الله عليه وسلم: «قد أجبتك». فقال الرجل للنبي صلى الله عليه وسلم: إني سائلك فمشدد عليك في المسألة، فلا تجد علي في نفسك؟ فقال: «سل عما بدا لك» فقال: أسألك بربك ورب من قبلك، آلله أرسلك إلى الناس كلهم؟ فقال: «اللهم نعم». قال: أنشدك بالله، آلله أمرك أن نصلي الصلوات الخمس في اليوم والليلة؟ قال: «اللهم نعم». قال: أنشدك بالله، آلله أمرك أن نصوم هذا الشهر من السنة؟ قال: «اللهم نعم». قال: أنشدك بالله، آلله أمرك أن تأخذ هذه الصدقة من أغنيائنا فتقسمها على فقرائنا؟ فقال النبي صلى الله عليه وسلم: «اللهم نعم». فقال الرجل: آمنت بما جئت به، وأنا رسول من ورائي من قومي، وأنا ضمام بن ثعلبة أخو بني سعد بن بكر.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 63]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:
Nígbà tí a jokoo pẹlu Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nínú mọṣalaaṣi, ọkùnrin kan ba wọlé lórí ràkúnmí, o da ràkúnmí rẹ̀ gunlẹ, o si dè é, lẹ́yìn naa o sọ fún wọn pé: Èwo ni Muhammad nínú yin? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si rọ̀gbọ̀kú láàrin wọn, ni a wa sọ pé: Ọkunrin pupa ti o rọ̀gbọ̀kú yii ni. Arákùnrin naa wa sọ fún un pé: Irẹ ọmọ Abdul Muttọlib, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Mo ti da ẹ lóhùn”. Arákùnrin naa wa sọ fún Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Maa bi ọ léèrè, ti mo si ma le mọ́ ọ lori ìbéèrè naa, ma ṣe bínú sí mi. O wa sọ pe: “Bèèrè ohun ti o ba fẹ”, o wa sọ pé: Mo fi Oluwa rẹ bẹ ọ ati Olúwa àwọn ti wọn ṣiwaju rẹ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O ran ọ si gbogbo àwọn èèyàn? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa ki irun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pé: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa gba aawẹ oṣù yii nínú ọdún? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki o gba sàká yii lọ́wọ́ àwọn olówó wa ki o si pin in fun awọn talika wa? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Bẹẹni”. Arákùnrin naa wa sọ pé: Mo gba ohun ti o mu wa gbọ́, èmi si ni ojiṣẹ fun awọn ijọ mi, emi ni Dimaam ọmọ Tha’labah, láti ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 63]
Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé: Nígbà tí àwọn saabe jókòó pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nínú mọṣalaaṣi, ni ọkùnrin kan ba wọlé lórí ràkúnmí, o wa da a gunlẹ, lẹ́yìn náà o si dè é, Lẹ́yìn naa o bi wọn leere pé: Ewo ninu yin ni Muhammad? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- rọgbọku láàrin àwọn èèyàn, ni a wa sọ pé: Ọkunrin pupa ti o rọgbọku yii ni, Ọkunrin naa sọ fun un pe: Iwọ ọmọ Abdul Muttalib, Ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fún un pé: Mo gbọ́ ẹ, bèèrè, maa da ẹ lóhùn. Arákùnrin naa wa sọ fún Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Dajudaju èmi maa bi ọ léèrè, mo si maa le mọ́ ọ nibi ibeere naa, ma ṣe binu si mi. Ìtumọ̀ ni pé: Ma bínú si mi, ma si jẹ ki ipọnju ba ọ, O sọ pé: Beere ohun ti o fẹ, O wa sọ pe: Mo n fi Olúwa rẹ àti Olúwa àwọn ti wọn ṣáájú rẹ bẹ̀ ọ́, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O ran ọ si awọn èèyàn? O sọ pé: Bẹẹni, lati fi kanpá mọ́ òdodo rẹ, Ọkùnrin náà sọ pé: ANSHUDUKA BILLAAH, itumọ rẹ ni pé: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa ki ìrun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́? Àwọn náà ni àwọn irun ọran-anyan, O sọ pe: Beeni, O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa gba aawẹ oṣù yìí ninu ọdún? Ìtumọ̀ rẹ ni: Oṣù Ramadan, O sọ pé: Bẹẹni, O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki o gba sàráà yii lọ́wọ́ awọn olowo wa ki o si pin in fun awọn talika wa? Oun naa ni sàká, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Bẹẹni, Dimaam wa gba Isilaamu, o wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé oun maa pe ìjọ oun sinu Isilaamu. Lẹ́yìn náà ni o wa ṣe àfihàn ara rẹ pé oun ni Dimaam ọmọ Tha’labah lati ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr.