عَنْ زِيَادِ بْنِ لَبِيدٍ رضي الله عنه قَالَ:
ذَكَرَ النَّبِيُّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ شَيْئًا، فَقَالَ: «ذَاكَ عِنْدَ أَوَانِ ذَهَابِ الْعِلْمِ» قُلْتُ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، وَكَيْفَ يَذْهَبُ الْعِلْمُ، وَنَحْنُ نَقْرَأُ الْقُرْآنَ وَنُقْرِئُهُ أَبْنَاءَنَا وَيُقْرِئُهُ أَبْنَاؤُنَا أَبْنَاءَهُمْ إِلَى يَوْمِ الْقِيَامَةِ؟ قَالَ: «ثَكِلَتْكَ أُمُّكَ زِيَادُ، إِنْ كُنْتُ لَأُرَاكَ مِنْ أَفْقَهِ رَجُلٍ بِالْمَدِينَةِ، أَوَلَيْسَ هَذِهِ الْيَهُودُ وَالنَّصَارَى يَقْرَؤونَ التَّوْرَاةَ وَالْإِنْجِيلَ، لَا يَعْمَلُونَ بِشَيْءٍ مِمَّا فِيهِمَا؟!».
[صحيح لغيره] - [رواه ابن ماجه] - [سنن ابن ماجه: 4048]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Ziyaad ọmọ Labiid- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ nǹkan kan, o wa sọ pé: “Ìyẹn nigba ti imọ bá lọ”, mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni imọ ṣe máa lọ ti a si n ka Kuraani, ti a si n mu awọn ọmọ wa ka a, ti àwọn ọmọ wa naa si n mu awọn ọmọ wọn ka a titi di ọjọ igbende? O sọ pe: “Ó ṣe fún ẹ, irẹ Ziyaad, ti mo si n lérò pé ó wa ninu awọn ti wọn ni agbọye ẹsin ju ninu ilu Mẹdina, ṣe àwọn Júù ati awọn Kristẹni o maa ka Taoreeta ati Injiila ni, ti wọn kò sì ṣiṣẹ pẹlu nǹkan kan ninu nǹkan ti o wa nínú méjèèjì?!”.
[O ni alaafia fun nnkan ti o yàtọ̀ si i] - [Ibnu Maajah ni o gba a wa] - [Sunanu ti Ibnu Maajah - 4048]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jókòó laarin awọn saabe rẹ, o wa sọ pé: Eyi ni àsìkò ti wọn maa ká imọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, Ziyaad ọmọ Labiid Al-Ansọọriy wá ṣe eemọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o wa beere lọwọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa sọ pé: Báwo ni wọ́n ṣe maa ká imọ kúrò lọ́dọ̀ wa?! Ti a si ti ka Kuraani ti a si ha a; mo fi Ọlọhun búra, a o maa ka a, a si maa jẹ ki awọn ìyàwó ati awọn ọmọ wa ka a, ati awọn ọmọ-ọmọ wa, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ẹni tí n ṣe eemọ pé: O ṣe fun ẹ, irẹ Ziyaad! Tí mo si n ka ọ kun ara àwọn onimimọ nínú àwọn ará ilu Mẹdina! Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé fun un pé: Pipadanu imọ kii ṣe pẹ̀lú pipadanu Kuraani; ṣùgbọ́n pipadanu imọ ni ki èèyàn má lò ó, Taoreeta ati Injiila n bẹ lọdọ awọn Juu ati awọn Kristẹni, tòun ti bẹ́ẹ̀ ko ṣe wọn ni anfaani, wọn ko si ṣe àǹfààní latara erongba àwọn méjèèjì; òun naa ni ki wọn lo ohun ti wọn mọ̀.