+ -

عن عبد الله بن عمرو رضي الله عنهما أن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«الرَّاحِمُونَ يَرْحَمُهمُ الرَّحمنُ، ارحَمُوا أهلَ الأرضِ يَرْحْمْكُم مَن في السّماء».

[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وأحمد] - [سنن أبي داود: 4941]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amri – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».

[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 4941]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye pe dajudaju awọn ti wọn maa n kẹ awọn ti wọn yatọ si wọn, Ọba Ajọkẹ aye naa o kẹ wọn pẹlu ikẹ Rẹ ti o kari gbogbo nkan; ní ti ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn).
Lẹyin naa ni o wa pa aṣẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pẹlu kikẹ gbogbo nkan ti o wa lori ilẹ ni eeyan tabi ẹranko tabi ẹyẹ tabi nkan ti o yatọ si i ninu awọn iran ẹda, ati pe ẹsan iyẹn naa ni ki Ọlọhun kẹ wọn lati oke awọn sanmọ Rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ẹsin Isilaamu ẹ̀sìn ikẹ ni, ti gbogbo rẹ si duro lori itẹle aṣẹ Ọlọhun ati ṣiṣe daadaa si ẹda.
  2. Ọlọhun – ti O tobi ti O gbọnngbọn - Ọba ti O ni ìròyìn ikẹ lara ni, ati pe Oun – mimọ fun un – ni Ajọkẹ aye Aṣakẹ orun, ti O si maa n mu ikẹ de ọdọ awọn ẹru Rẹ.
  3. Iru iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan ti yio gba, nitori naa awọn ti wọn ba maa n kẹ eeyan Ọlọhun a kẹ awọn naa.
Àlékún