عَن أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«يَأْتِي الشَّيْطَانُ أَحَدَكُمْ فَيَقُولُ: مَنْ خَلَقَ كَذَا؟ مَنْ خَلَقَ كَذَا؟ حَتَّى يَقُولَ: مَنْ خَلَقَ رَبَّكَ؟ فَإِذَا بَلَغَهُ فَلْيَسْتَعِذْ بِاللهِ وَلْيَنْتَهِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3276]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta ni o ṣẹda èyí? Ta ni o ṣẹda èyí? Titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Ti o ba ti ba a de ibẹyẹn, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ki o si jawọ.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3276]
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọrọ nipa iwosan ti o ṣe anfaani fun awọn ibeere ti èṣù fi n ko royiroyi ba olugbagbọ, Èṣù o maa sọ pé: Ta ni o ṣẹda eyi? Ta ni o ṣẹda eyi? Ta ni o ṣẹda sanmọ? Ta ni o ṣẹda ilẹ? Olugbagbọ yoo da a lohun ni ti ẹsin ati ti adamọ ati ti laakaye pẹlu ọrọ rẹ pé: Ọlọhun ni, Ṣùgbọ́n èṣù ko nii duro sibi aala yii ninu awọn royiroyi, bi ko ṣe pe yoo kúrò nibẹ titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Nibi ìyẹn ni olugbagbọ ti maa da awọn royiroyi yii padà pẹlu awọn alamọri mẹta kan:
Nini igbagbọ ninu Ọlọhun.
Wiwa isọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ èṣù.
Kiko ara ro nibi titẹsiwaju pẹlu awọn royiroyi.