عن أبي مسعود رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«إِذَا أَنْفَقَ الرَّجُلُ عَلَى أَهْلِهِ يَحْتَسِبُهَا فَهُوَ لَهُ صَدَقَةٌ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 55]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Tí ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti o n reti ẹsan rẹ lọdọ Ọlọhun, saara ni o jẹ fun un”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 55]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti inawo wọn jẹ dandan fun un, gẹgẹ bii iyawo rẹ ati awọn obi rẹ mejeeji ati ọmọ rẹ ati awọn ti wọn yatọ si wọn, ti o n fi ìyẹn sunmọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti o n reti ẹsan nnkan ti o n na lọdọ Rẹ, dajudaju ẹsan saara n bẹ fun un.