+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ:
قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «إِنَّ اللَّهَ قَالَ: مَنْ عَادَى لِي وَلِيًّا فَقَدْ آذَنْتُهُ بِالحَرْبِ، وَمَا تَقَرَّبَ إِلَيَّ عَبْدِي بِشَيْءٍ أَحَبَّ إِلَيَّ مِمَّا افْتَرَضْتُ عَلَيْهِ، وَمَا يَزَالُ عَبْدِي يَتَقَرَّبُ إِلَيَّ بِالنَّوَافِلِ حَتَّى أُحِبَّهُ، فَإِذَا أَحْبَبْتُهُ: كُنْتُ سَمْعَهُ الَّذِي يَسْمَعُ بِهِ، وَبَصَرَهُ الَّذِي يُبْصِرُ بِهِ، وَيَدَهُ الَّتِي يَبْطِشُ بِهَا، وَرِجْلَهُ الَّتِي يَمْشِي بِهَا، وَإِنْ سَأَلَنِي لَأُعْطِيَنَّهُ، وَلَئِنِ اسْتَعَاذَنِي لَأُعِيذَنَّهُ، وَمَا تَرَدَّدْتُ عَنْ شَيْءٍ أَنَا فَاعِلُهُ تَرَدُّدِي عَنْ نَفْسِ المُؤْمِنِ، يَكْرَهُ المَوْتَ وَأَنَا أَكْرَهُ مَسَاءَتَهُ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6502]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:
Ojiṣẹ Ọlọhun - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹni ti o ba mu aayo mi ni ọta, Mo ti kede ogun pẹlu rẹ, ati pe ẹru Mi o nii sunmọ Mi pẹlu nkankan ti Mo nífẹ̀ẹ́ si ju nkan ti Mo ṣe ni ọranyan fun un lọ, àti pe ẹru Mi ko nii yẹ ko nii gbo lẹni ti yio maa sunmọ Mi pẹlu awọn aṣegbọrẹ titi ti maa fi nífẹ̀ẹ́ rẹ, ti Mo ba ti wa nífẹ̀ẹ́ rẹ: Maa di igbọrọ rẹ ti yoo fi maa gbọrọ, maa di iriran rẹ ti yio fi maa riran, maa si di ọwọ rẹ ti yio fi maa mu nkan, Maa si tun di ẹsẹ rẹ ti yio fi maa rin, ti o ba wa bi Mi leere maa fun un, ti o ba si tun wa iṣọra pẹlu Mi maa sọ ọ, Mi o fa sẹyin nibi nkankan ti Mo fẹ ṣe bii ifasẹyin Mi nibi gbigba ẹmi mumini, ti o n korira iku ti Emi naa si n korira fifi ara ni in».

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6502]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo ninu hadīth qudusiy pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn sọ pe: Ẹni ti o ba fi suta kan aayo kan ninu awọn aayo Mi, ti o wa mu inu bi i, ti o tun korira rẹ, Mo ti fi mọ ọn Mo si ti kede ibasọta fun un.
Ati pe aayo Ọlọhun ni: Mumini olupaya, ati pe lori odiwọn nkan ti n bẹ fun ẹru ni igbagbọ ati ipaya ni yio maa jẹ ipin rẹ nibi ijẹ aayo Ọlọhun. Ati pe musulumi o nii maa sunmọ Oluwa rẹ pẹlu nkankan ti yoo nífẹ̀ẹ́ si ju nnkan ti O ṣe ni ọranyan ti O si tun ṣe ni dandan lọ ninu ṣiṣe awọn nǹkan ti sharia pàṣẹ rẹ ati gbigbe awọn eewọ jusilẹ, ati pe musulumi o nii yẹ ko nii gbo lẹni ti yio maa sunmọ Oluwa rẹ pẹlu awọn aṣegbọrẹ mọ awọn ọranyan; titi ti ọwọ rẹ o fi tẹ ifẹ Ọlọhun. Ti Ọlọhun ba ti wa nífẹ̀ẹ́ rẹ, Ọlọhun ni yio maa tọ́ ọ sọ́nà nibi awọn oríkèé ara mẹrẹẹrin yii:
Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi igbọrọ rẹ, nitori naa ko nii gbọ́ nkankan ayaafi nkan ti yoo yọ Ọlọhun ninu.
Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi iriran rẹ, nitori naa ko nii wo nkankan ayaafi nkan ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si wiwo o ti O si tun yọnu si i.
Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi ọwọ rẹ, nítorí naa ko nii fi ọwọ rẹ ṣe nkankan ayaafi nkan ti yio yọ Ọlọhun ninu.
Yoo tun tọ ọ sọ́nà nibi ẹsẹ rẹ, nitori naa ko nii maa rin ayaafi lọ sibi nkan ti yio yọ Ọlọhun ninu, ko si nii maa ṣe igbiyanju ayaafi sibi nkan ti oore wa nibẹ.
Pẹlu eyi, ti o ba bi Ọlọhun leere nkankan dajudaju Ọlọhun O fun un ni nkan ti o beere, nitori naa yio jẹ ẹni ti adua rẹ o maa gba, ti o ba si tun wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ti o tun sadi I lẹni ti n wa aabo, dajudaju Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un O ṣọ ọ, yoo si tun da aabo bo o nibi nkan ti o n paya.
Lẹyin naa ni Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Mi o fa sẹyin nibi nkankan ti Mo fẹ ṣe bii ifasẹyin Mi nibi gbigba ẹmi Mumini ni ti ikaaanu rẹ; nítorí pé o korira iku latari inira ti o wa nibẹ, ati pe Ọlọhun si korira nkan ti yio maa ni mumini lara.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Hadīth yii ninu awọn ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ ni, ti wọn si maa n pe é ni Hadīth Al-Qudusiy tabi Al-Ilaahiy, oun si ni eyi ti o ṣe pe gbolohun rẹ ati itumọ rẹ wa lati ọdọ Ọlọhun, yatọ si pe ko ni awọn ìròyìn ẹsa Alukuraani ti o fi da yatọ si awọn miran, bii mimaa jọsin pẹlu kika rẹ ati ṣiṣe imọra fún un, ati ipenija ati idalagara, ati èyí tí o yàtọ̀ si i.
  2. Kikọ kuro nibi fifi ṣuta kan awọn aayo Ọlọhun ati ṣiṣenilojukokoro síbi ninifẹẹ wọn, ati fifi ọla wọn rinlẹ.
  3. Pipa àṣẹ pẹlu biba awọn ọta Ọlọhun ṣe ọta ati ṣíṣe ìní ìfẹ́ wọn ni eewọ.
  4. Ẹni ti o ba pe apemọra ijẹ aayo Ọlọhun lai tẹle ofin Rẹ, opurọ ni in nibi apemọra rẹ.
  5. Ọwọ a maa tẹ jijẹ aayo Ọlọhun pẹlu ṣiṣe awọn ọranyan ati gbigbe awọn eewọ jusilẹ.
  6. Ninu awọn okunfa ifẹ Ọlọhun si ẹru Rẹ ati jijẹ ipe adua rẹ ni ṣiṣe awọn aṣegbọrẹ lẹyin ṣiṣe awọn ọranyan ati gbigbe awọn eewọ jusilẹ.
  7. Ẹri lori iyi awọn aayo Ọlọhun ati giga ipo wọn.
Àlékún