+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ:
عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ: «قَالَ اللَّهُ: كَذَّبَنِي ابْنُ آدَمَ وَلَمْ يَكُنْ لَهُ ذَلِكَ، وَشَتَمَنِي وَلَمْ يَكُنْ لَهُ ذَلِكَ، فَأَمَّا تَكْذِيبُهُ إِيَّايَ فَقَوْلُهُ: لَنْ يُعِيدَنِي، كَمَا بَدَأَنِي، وَلَيْسَ أَوَّلُ الخَلْقِ بِأَهْوَنَ عَلَيَّ مِنْ إِعَادَتِهِ، وَأَمَّا شَتْمُهُ إِيَّايَ فَقَوْلُهُ: اتَّخَذَ اللَّهُ وَلَدًا وَأَنَا الأَحَدُ الصَّمَدُ، لَمْ أَلِدْ وَلَمْ أُولَدْ، وَلَمْ يَكُنْ لِي كُفْؤًا أَحَدٌ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 4974]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurairah- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: “Ọlọhun sọ pe: Ọmọ Adam pe Mi ni opurọ, ko si tọ fun un, o si bu mi, ko si tọ fun un, pipe ti o pe Mi ni opurọ ni ọrọ rẹ ti o sọ pe: Ko lee da mi pada gẹgẹ bi O ṣe da mi ni akọkọ, akọkọ ẹ̀dá ko si rọrùn fun mi ju dida a pada lọ, ṣùgbọ́n èébú tí ó bu Mi ni ọrọ rẹ ti o sọ pe: Ọlọhun ni ọmọ, Ọkan ṣi ni Mi, Ajironukan ni Mi, Mi o bímọ, wọn o si bi Mi, ko si si ẹni kan ti o jọ Mi".

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4974]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé ninu haiisi kudsiy pe Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn sọ nípa àwọn ọṣẹbọ ati awọn Kèfèrí pe wọn n pe Oun ni opurọ, wọn si n ròyìn Rẹ pẹlu abuku, ìyẹn ko si tọ fun wọn.
Nipa pipe E ni opurọ ni: ero wọn pe Ọlọhun ko lee da wọn pada lẹyin iku wọn gẹgẹ bi O ṣe da wọn ni akọkọ lati ibi àìsí, O wa fesi fun wọn pe Ẹni ti O bẹrẹ dida ẹ̀dá lati ibi àìsí ni ikapa lati da wọn pada, koda oun ni o rọrùn jù, bi o ti lẹ je pe bákan náà ni mejeeji ṣe ri ni ọdọ Ọlọhun ati dida ati dida pada, Ọlọhun ni ikapa lórí gbogbo nnkan.
Ni ti eebu wọn: oun ni ọrọ wọn pe: O ni ọmọ, O wa fesi fun wọn pe Ọkan ni Oun, Oun si da ni gbogbo pipe nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn iṣe Rẹ, O mọ kuro nibi gbogbo àléébù, Ajironukan ni ti ko bukaata si ẹni kankan, ti gbogbo èèyàn si n bukaata si I, ko bi ọmọ kankan, ko si jẹ ọmọ fun ẹni kankan, ko si si ẹni ti o jọ Ọ, mimọ ni fun Un.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Fifi pipe agbára rinlẹ fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  2. Fifi àjíǹde lẹ́yìn ikú rinlẹ.
  3. Ijẹ Kèfèrí ẹni tí o ba tako igbedide tabi ti o fi ọmọ ti si ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  4. Ko si ẹni ti o da bii Ọlọhun.
  5. Gbígbòòrò suuru Ọlọhun, ati lilọ àwọn Kèfèrí lara bóyá wọn le ronupiwada.
Àlékún