عن عبد الله بن مسعود رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ قَرَأَ حَرْفًا مِنْ كِتَابِ اللهِ فَلَهُ بِهِ حَسَنَةٌ، وَالْحَسَنَةُ بِعَشْرِ أَمْثَالِهَا، لَا أَقُولُ {الم} حَرْفٌ، وَلَكِنْ {أَلِفٌ} حَرْفٌ، وَ{لَامٌ} حَرْفٌ، وَ{مِيمٌ} حَرْفٌ».
[حسن] - [رواه الترمذي] - [سنن الترمذي: 2910]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ, mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alifu harafi kan ni, lāmu naa harafi kan ni, mīmu naa harafi kan ni».
[O daa] - [Tirmiziy ni o gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2910]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wípé dajudaju gbogbo Musulumi kọọkan ti o ba n ka harafi kan ninu tira Ọlọhun ni ẹsan kọọkan a máa bẹ fun un, ti wọn yio si ṣe adipele ẹsan naa fun un ni ilọpo mẹwaa iru rẹ.
Lẹyin naa ni o wa ṣalaye pẹlu gbolohun rẹ ti o sọ pe: (Mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alif harafi kan ni, lām naa harafi kan ni, mīm naa harafi kan ni): Nítorí naa yio jẹ harafi mẹta ti o ko ẹsan ọgbọn sinu.