عن أبي مسعود رضي الله عنه قال: قال النبي صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ قَرَأَ بِالْآيَتَيْنِ مِنْ آخِرِ سُورَةِ الْبَقَرَةِ فِي لَيْلَةٍ كَفَتَاهُ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5009]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5009]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe dajudaju ẹni tí o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni alẹ, dajudaju Ọlọhun a to o kuro nibi aburu ati nkan ti ko dáa, wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi didide loru (irun oru), wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi awọn iranti yòókù, wọn tun sọ pe: Dajudaju mejeji ni odiwọn ti o kere ju ti o le to ninu kika Kuraani nibi idide oru (irun oru), wọn si tun sọ nkan ti o yatọ si ìyẹn, ati pe o sunmọ pe gbogbo nkan ti wọn sọ yẹn naa ni o daa ti gbolohun yẹn naa si ko o sinu.