+ -

عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بْنِ عَمْرٍو رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا:
أَنَّ رَجُلًا سَأَلَ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: أَيُّ الإِسْلاَمِ خَيْرٌ؟ قَالَ: «تُطْعِمُ الطَّعَامَ، وَتَقْرَأُ السَّلاَمَ عَلَى مَنْ عَرَفْتَ وَمَنْ لَمْ تَعْرِفْ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -:
Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu wo lo fi n loore julọ? O sọ pe: «Ki o maa funni ni ounjẹ, ki o si tun maa salamọ si ẹni ti o mọ ati ẹni ti o ko mọ».

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Wọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Awọn iwa Isilaamu wo lo fi n lọla julọ? Ni o wa darukọ awọn iwa meji:
Alakọkọọ: Pipọ ni imaa fun awọn alaini ni ounjẹ, ti saara ati ẹbun ati igbalejo ati ikolẹnujọ sì tun wọ inu rẹ, ati pe ọla ifunni l'ounjẹ tun kanpa ni awọn asiko ebi ati ọwọn gogo.
Ẹlẹẹkeji ni: Sisalamọ si gbogbo musulumi, o mọ ọn ni tabi o ko tiẹ mọ ọn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Ti èdè Sawahili Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe ojukokoro awọn saabe lori mimọ awọn iwa ti yio ṣe anfaani ni aye ati ọjọ ikẹyin.
  2. Sisalamọ ati fifunni l'ounjẹ wa ninu awọn iṣẹ ti o fi n lọla julọ ninu Isilaamu; latari ọla ti n bẹ fun un ati nini bukaata awọn eeyan si i ni gbogbo asiko.
  3. Ṣiṣe daadaa pẹlu ọrọ ati iṣe papọ pẹlu awọn iwa mejeeji yii, ati pe oun naa si ṣiṣe daadaa ti o fi n pe julọ.
  4. Awọn iwa yii nii ṣe pẹlu ajọṣepọ awọn Musulumi laarin ara wọn, awọn iwa kan ṣi wa ti o nii ṣe pẹlu ajọṣepọ laarin ẹru ati Olowo rẹ (Allāhu).
  5. Imaa bẹrẹ pẹlu salamọ jẹ ẹsa laarin awọn Musulumi, nitori naa wọn o gbọdọ kọkọ salamọ si keferi.