عن عمرو بن شُعيب عن أبيه عن جدِّه قال: قال رسولُ الله صلى الله عليه وسلم:
«مُرُوا أولادكمِ بالصلاةِ وهم أبناءُ سبعِ سِنينَ، واضرِبوهم عليها وهم أبناءُ عَشرٍ، وفرِّقوا بينهم في المَضاجِعِ».
[حسن] - [رواه أبو داود] - [سنن أبي داود: 495]
المزيــد ...
Lati ọdọ Amru ọmọ Shu'aib lati ọdọ baba rẹ lati ọdọ baba baba rẹ, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ẹ pa awọn ọmọ yin láṣẹ pẹlu irun ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun meje, ẹ na wọn lori rẹ ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun mẹwaa, ẹ ṣe opinya laaarin wọn nibi awọn ibusun".
[O daa] - [Abu Daud ni o gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 495]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju o jẹ dandan lori baba lati pa awọn ọmọ rẹ láṣẹ- lọkunrin ati lobinrin- pẹlu irun ti awọn ọjọ ori wọn ba wa ni ọdun meje, ki o si kọ wọn ni nnkan ti wọn bukaata si lati gbe e duro. Ti wọn ba ti pe ọdun mẹwaa, o maa lekun ninu alamọri náà, o maa na wọn lori aṣeeto nibẹ, o si maa ya wọn nibi ibùsùn.