+ -

عَنِ النُّعْمَانِ بْنِ بَشِيرٍ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«مَثَلُ الْمُؤْمِنِينَ فِي تَوَادِّهِمْ وَتَرَاحُمِهِمْ وَتَعَاطُفِهِمْ مَثَلُ الْجَسَدِ، إِذَا اشْتَكَى مِنْهُ عُضْوٌ تَدَاعَى لَهُ سَائِرُ الْجَسَدِ بِالسَّهَرِ وَالْحُمَّى».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ An-Nu‘mān ọmọ Bashīr - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona.

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan ki ìṣesí awọn Musulumi pẹlu ara wọn o maa jẹ nibi nini ifẹ daadaa ati ikẹ ati ikunlọwọ ati aranṣe, ati titara pẹlu nkan ti o ba ṣẹlẹ si wọn ni inira, gẹgẹ bii ara kan soso, nigba ti oríkèé kan ninu rẹ ba ṣe aisan, gbogbo ara ni yio ba a ṣe papọ nibi aisun ati igbona.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Ti èdè Sawahili Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. O tọ (o jẹ dandan) gbigbe awọn iwọ awọn Musulumi tobi ati ṣiṣe ojukokoro lori ikun wọn lọwọ ati ki apakan wọn o maa ṣàánú apa miran.
  2. O tọ (o jẹ dandan) ki o maa bẹ laarin awọn olugbagbọ ifẹ ati aranṣe.