عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّهُ سَمِعَ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«أَرَأَيْتُمْ لَوْ أَنَّ نَهَرًا بِبَابِ أَحَدِكُمْ يَغْتَسِلُ فِيهِ كُلَّ يَوْمٍ خَمْسًا، مَا تَقُولُ ذَلِكَ يُبْقِي مِنْ دَرَنِهِ؟» قَالُوا: لَا يُبْقِي مِنْ دَرَنِهِ شَيْئًا، قَالَ: «فَذَلِكَ مِثْلُ الصَّلَوَاتِ الخَمْسِ، يَمْحُو اللَّهُ بِهِ الخَطَايَا».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 528]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju o gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
"Ẹ sọ fun mi ti akeremọdo kan ba wa ni ẹnu ọ̀nà ẹni kọọkan ninu yin ti o n wẹ nibẹ ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, njẹ ìyẹn le ṣẹ nǹkan kan kù nínú ìdọ̀tí rẹ bi?" wọn sọ pe: Ko lee ṣẹ nnkan kan ku ninu ìdọ̀tí rẹ, o sọ pe: "Gẹgẹ bẹẹ ni iru awọn irun maraarun-un, Ọlọhun maa n pa awọn àṣìṣe rẹ pẹlu rẹ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 528]
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi àwọn irun maraarun-un lojoojumọ nibi imukuro rẹ ati pipa awọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ ati awọn àṣìṣe, o fi we akeremọdo kan ti o wa ni ẹnu ọ̀nà ọmọniyan ti o n wẹ ninu rẹ lojoojumọ ni ẹẹmaraun-un, ti ko nii ṣẹ nnkan kan ku ninu ìdọ̀tí rẹ ati ẹgbin rẹ.