عن عبد الله بن مسعود رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«إنَّ الرُّقَى والتَمائِمَ والتِّوَلَةَ شِرْكٌ».
[صحيح] - [رواه أبو داود وابن ماجه وأحمد] - [سنن أبي داود: 3883]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'hud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni”
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 3883]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé àwọn nǹkan ti ṣíṣe wọn wa ninu ẹbọ, ninu wọn ni:
Akọkọ: Ọfọ̀: Oun ni ọ̀rọ̀ ti àwọn ara àsìkò ki Isilaamu to de fi maa n ṣe ìwòsàn, ti o ni ẹbọ nínú.
Ìkejì: Àsokọ́ra lati ara ìlẹ̀kẹ̀ ati nǹkan ti o jọ ọ: Eyi ti wọn maa n so kọ ọmọdé lọrun, ati awọn ẹran-ọ̀sìn, ati nǹkan ti o yatọ si i, lati ti ojukoju dànù.
Ikẹta: Oogun ifẹran: Eyi ti wọn ṣe lati jẹ ki ọkọ ati ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ara wọn.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí wa nínú ẹbọ; torí pé o wa ninu fifi nǹkan ṣe okùnfà, ti kii sii ṣe okùnfà ti o ba òfin mu ti o rinlẹ pẹ̀lú ẹ̀rí, kii sii ṣe okùnfà ti ìmọ̀lára ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí. Ṣùgbọ́n àwọn òkùnfà ti o ba ofin mu gẹ́gẹ́ bii kika Kuraani, tabi eyi ti o jẹ ti ìmọ̀lára gẹ́gẹ́ bii àwọn oògùn ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí, èyí ni ẹtọ pẹlu adisọkan pe okùnfà ni, ati pe àǹfààní ati ìnira wa lọ́wọ́ Ọlọhun.