عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«أَتَدْرُونَ مَا الْغِيبَةُ؟»، قَالُوا: اللهُ وَرَسُولُهُ أَعْلَمُ، قَالَ: «ذِكْرُكَ أَخَاكَ بِمَا يَكْرَهُ»، قِيلَ: أَفَرَأَيْتَ إِنْ كَانَ فِي أَخِي مَا أَقُولُ؟ قَالَ: «إِنْ كَانَ فِيهِ مَا تَقُولُ فَقَدِ اغْتَبْتَهُ، وَإِنْ لَمْ يَكُنْ فِيهِ فَقَدْ بَهَتَّهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2589]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Njẹ ẹ mọ ohun ti n jẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn?”, wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ ju, o sọ pé: “Oun naa ni ki o maa sọ nipa ọmọ-ìyá rẹ ohun ti o korira”, wọn sọ pé: Ti ohun ti mo n sọ ba n bẹ lara ọmọ-ìyá mi ńkọ́? O sọ pe: “Ti ohun ti o n sọ ba n bẹ lara ọmọ-iya rẹ, o ti sọ ọrọ rẹ lẹ́yìn nìyẹn, ṣùgbọ́n ti ko ba si lara rẹ, o ti dá àdápa irọ́ mọ ọn nìyẹn”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2589]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pàápàá ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn ti o jẹ eewọ, oun naa ni: Sísọ nipa Mùsùlùmí ti ko si ni tòsí ohun ti o maa korira, bóyá o jẹ nibi awọn ìròyìn rẹ ti wọn dá mọ ọn tabi ti ìwà, gẹgẹ bii: Olojukan ẹlẹtan òpùrọ́, ati awọn nǹkan ti o jọ ọ ninu awọn ìròyìn ẹ̀gàn, kódà ki ìròyìn náà o wa lára rẹ.
Ṣùgbọ́n ti iroyin naa ko ba si lara rẹ, eyi tun buru ju ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn lọ, oun ni BUHTAAN, itumọ rẹ ni: Adapa irọ mọ ọmọniyan pẹ̀lú nǹkan ti ko si lára rẹ.