عَنْ أَبٍي سَعِيدٍ الخُدْرِيَّ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ:
أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ جَلَسَ ذَاتَ يَوْمٍ عَلَى المِنْبَرِ وَجَلَسْنَا حَوْلَهُ، فَقَالَ: «إِنِّي مِمَّا أَخَافُ عَلَيْكُمْ مِنْ بَعْدِي، مَا يُفْتَحُ عَلَيْكُمْ مِنْ زَهْرَةِ الدُّنْيَا وَزِينَتِهَا» فَقَالَ رَجُلٌ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، أَوَيَأْتِي الخَيْرُ بِالشَّرِّ؟ فَسَكَتَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَقِيلَ لَهُ: مَا شَأْنُكَ؟ تُكَلِّمُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ وَلاَ يُكَلِّمُكَ؟ فَرَأَيْنَا أَنَّهُ يُنْزَلُ عَلَيْهِ؟ قَالَ: فَمَسَحَ عَنْهُ الرُّحَضَاءَ، فَقَالَ: «أَيْنَ السَّائِلُ؟» وَكَأَنَّهُ حَمِدَهُ، فَقَالَ: «إِنَّهُ لاَ يَأْتِي الخَيْرُ بِالشَّرِّ، وَإِنَّ مِمَّا يُنْبِتُ الرَّبِيعُ يَقْتُلُ أَوْ يُلِمُّ، إِلَّا آكِلَةَ الخَضْرَاءِ، أَكَلَتْ حَتَّى إِذَا امْتَدَّتْ خَاصِرَتَاهَا اسْتَقْبَلَتْ عَيْنَ الشَّمْسِ، فَثَلَطَتْ وَبَالَتْ، وَرَتَعَتْ، وَإِنَّ هَذَا المَالَ خَضِرَةٌ حُلْوَةٌ، فَنِعْمَ صَاحِبُ المُسْلِمِ مَا أَعْطَى مِنْهُ المِسْكِينَ وَاليَتِيمَ وَابْنَ السَّبِيلِ - أَوْ كَمَا قَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ - وَإِنَّهُ مَنْ يَأْخُذُهُ بِغَيْرِ حَقِّهِ، كَالَّذِي يَأْكُلُ وَلاَ يَشْبَعُ، وَيَكُونُ شَهِيدًا عَلَيْهِ يَوْمَ القِيَامَةِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 1465]
المزيــد ...
Láti ọdọ bàbá Sa'eed Al-Khudriy ki Ọlọhun yọnu si:
Dájúdájú Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) o joko ni ọjọ kan lórí minbari ti awa si joko ní ẹgbẹ rẹ, ló bá sọ pé: "dájúdájú ninu nkan ti emi nbẹru fún nípa yin ti mo bá lọ tán ni yodoyindin aye àti ọsọ rẹ ti wọn yóò si fún yín" ni arákùnrin kan bá sọ pé: mope irẹ Ojisẹ Ọlọhun: ṣe oore le tun mu aburú wa ni? Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) bá dakẹ kò sọrọ, ni wọn bá sọ fún arákùnrin náà pé: kí ló ṣe ọ? o nba Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọrọ kò si bá ọ sọrọ? la bá ri pé Qur'an nsọkalẹ fún Anọbi lọwọ ni? ó sọ pé: ni o ba nnu oogun kúrò ní ara rẹ, ni o ba sọ pé: "nibo ni onibeerè náà wà? "bi ẹni pé o yin-in, lo bá wa sọ fun pe: "kii ṣe pé oore a máa mú aburú wa, dájúdájú irúgbìn iṣẹ palẹ ojo o le pa ẹranko tí ó jẹ tàbí kó fẹẹ pa á ayaafí tí eranko náà bá jẹ nibẹ, ti o si ri pé inú ti kun kẹkẹ ti o fi ewéko náà silẹ o lọ yeerun osi náà tọtọ, o tọ o yagbẹ o tun fi ẹnu jẹ koríko lọ, dájúdájú owo tabi dukia yi ni ewéko tútù to dùn, mandala eyi ti yóò mọ bẹ pẹlu musulumi nínú èyí tí o ná fún alaini ọmọ orukan àti onírin àjò - tabi gẹgẹ bí Anọbi ṣe sọ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - eni tó bá gba dukia náà láì ṣe ọna ẹtọ o da bí ẹni tí njẹ un ti ko yo ni, yóò sì jẹ ibalẹjọ fun ni ọjọ igbende.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1465]
Anọbi - kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - joko lẹ ori minbari ni ọjọ kan ti mbá awọn ọmọ lẹyìn rẹ sọrọ, o si ṣọ pe:
dájúdájú eyí ti o pọ ti mo nbẹru tí mo sì npáya fún nípa yin lẹyin mi ni ohun tí wọn yóò ṣi silẹ fún yin nínú àwọn ìbùkún ilẹ ati aye ati ọsọ rẹ àti ẹwà rẹ ati awọn orisirisi igbadun ati aṣọ ati awọn irúgbìn àti awọn nkan míran ti awọn eniyan ma fi nse iyanran àti akọ to un ti pé isẹku rẹ kéré.
Ni arákùnrin kan bá sọ pé: ọsọ aye idẹra lo jẹ láti ọdọ Ọlọhun, se idẹra yi yoo tun pada di iya ati ìbáwí ni bi?!
ni awọn eniyan ba bu onibeere naa nigbati wọn ri pe Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Re máa ba a) dakẹ ti kò sọrọ, wọn ro pé oti mu Anọbi binu ni.
O padà wá hàn pé dájúdájú Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ngba waayi kuraani lọ wọ (Kuraani nsọ kalẹ fun) o wa bẹrẹ síní nu oogun ojú rẹ kúrò, o wa sọ pé: onibeere náà dà?
O sọ pé: emi ni.
Anọbi dupẹ fún Ọlọhun o si fi iyin fun, leyin náà ni o sọ pé: oore gangan koni mu nkan wa ju oore lọ, ṣugbọn nkan yindin won yi kii se oore pọnbele nítorí awọn wahala ati ifiga gbága lórí rẹ ati igbaju mọ ti kii jẹ ki a le gbaju mọ ọrun ni pípé, lẹyin naa ni o wa se àpèjúwe rẹ, o sọ pé: dájúdájú irúgbìn iṣẹ palẹ ojo ati titutu rẹ; òhun ni iru irúgbìn kan ti aa ma wu ewurẹ tabi àgùntàn lati jẹ ẹ, ti o bá jẹ pẹlu parahan ati wọbia yóò pa tabi ko fẹ pa a, ayaafi ẹran ti o jẹ ewé tutu yi ti ẹgbẹ kan inu rẹ bá ti kun yóò fi yoku silẹ, leyin náà yóò kọjú sí òòrùn lati sinmi, yóò jagbẹ yóò tó bẹẹ ni yóò gbé awon eyi to kù ni enu rẹ mi, lẹyìn naa yóò tún padà sí bẹ lati jẹ.
dájúdájú dukiya yi bi ewéko to tutù daada ni ti o si dùn, ọpọ rẹ le pani tabi ki o fẹẹ pani; ayaafi ti o ba jẹ diẹ ti o ni bukaata si ti yóò sì tó ní ọna ẹtọ, irú bẹ ko nii mu ìnira lọwọ, idẹra musulumi ohun ni ẹnití o bá aláìní ati ọmọ orukan ati onírinàjò ninu rẹ, ẹnití o bá gbà pẹlu ẹtọ rẹ wọn yóò fi ibukún si fun, ẹni tí o bá gba a láì ṣe pẹlu ẹtọ rẹ àpèjúwe rẹ o dà gẹgẹ bi ẹnití njẹ un tiko yó, yóò padà jẹ ibalẹjo fún un ni ọjọ igbende.