عن سعد بن أبي وقاص رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«إِنَّ اللهَ يُحِبُّ الْعَبْدَ التَّقِيَّ الْغَنِيَّ الْخَفِيَّ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2965]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Sahd ọmọ Abu Waqqaas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Dájúdájú Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ẹrú ti o jẹ olupaya ọlọ́rọ̀ ti o pamọ́”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2965]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si awọn kan ninu awọn ẹru Rẹ,
Ninu wọn ni olupaya: Ẹni ti n tẹle àṣẹ Ọlọhun, ti n jìnnà si awọn nǹkan ti O kọ̀.
O tun nífẹ̀ẹ́ si ọlọrọ: Ẹni ti o rọrọ̀ pẹ̀lú Ọlọhun kuro lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, kii ṣíjú wo ẹlòmíràn.
O tun nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ó pamọ́: Ẹni ti o ni ìtẹríba, ti maa n sin Oluwa rẹ, ti n kó airoju pẹ̀lú nǹkan ti yóò ṣe é ni anfaani, ti kii ni akolekan si ki ẹni kan kan mọ oun, tabi ki wọn maa yin oun.