+ -

عن معاوية رضي الله عنه قال: سمعت النبي صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَنْ يُرِدِ اللهُ بِهِ خَيْرًا يُفَقِّهْهُ فِي الدِّينِ، وَإِنَّمَا أَنَا قَاسِمٌ، وَاللهُ يُعْطِي، وَلَنْ تَزَالَ هَذِهِ الْأُمَّةُ قَائِمَةً عَلَى أَمْرِ اللهِ، لَا يَضُرُّهُمْ مَنْ خَالَفَهُمْ، حَتَّى يَأْتِيَ أَمْرُ اللهِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 71]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Muaawiyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ́ oore fun, yoo fun un ni agbọye ninu ẹsin, olùpín ni mi, Ọlọhun ni n fúnni, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti àṣẹ Ọlọhun yoo fi dé”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 71]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fun, O maa fun un ni agbọye ninu ẹsin Rẹ, oun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ni olupin, o maa n pin ohun ti Ọlọhun ba fun un ninu arisiki ati imọ ati awọn nǹkan mìíràn, ati pe ẹni ti n fúnni gan ni Ọlọhun, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n o kii ṣe olohun jẹ okùnfà ti ko lee ṣe anfaani kankan ayafi pẹ̀lú iyọnda Ọlọhun, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti ayé fi maa parẹ”

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titobi ati ọla ti n bẹ fun imọ sharia ati kikọ ọ, ati ṣisẹnilojukokoro lori ẹ.
  2. Diduro ti òdodo gbọdọ wa ninu ijọ yii, ti àwọn ikọ̀ kan ba ti pa á tì, àwọn ikọ̀ mìíràn maa dúró tì í.
  3. Níní agbọye ninu ẹsin wa ninu pe Ọlọhun fẹ oore fun ẹrú rẹ.
  4. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n fúnni pẹ̀lú àṣẹ Ọlọhun ati fífẹ́ Rẹ, ati pe ko ni ikapa nǹkan kan.