عن أنس بن مالك رضي الله عنه:
أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَانَ لَا يَرُدُّ الطِّيبَ.

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 2582]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe:
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii da lọ́fíńdà padà.

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2582]

Àlàyé

Ninu ìlànà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni pe kii da lọfinda padà, o si maa n gbà á; torí pé o fúyẹ́ ni gbígbé, òórùn rẹ si dára.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. A fẹ ki a gba ẹbun lọfinda; torí pé ko si ipese kan kan fun gbígbé e, ko si si ìrègún nibi gbigba a.
  2. Pípé ati dídára ìwà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi pe kii da lọ́fíńdà pada, ati gbigba ẹ̀bùn lọ́wọ́ ẹni tí ó bá fún un.
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori lílo lọ́fíńdà.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (63)