عَنْ عَبْدِ اللهِ بْنِ عَمْرٍو رَضيَ اللهُ عنهما قَالَ:
رَجَعْنَا مَعَ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ مِنْ مَكَّةَ إِلَى الْمَدِينَةِ حَتَّى إِذَا كُنَّا بِمَاءٍ بِالطَّرِيقِ تَعَجَّلَ قَوْمٌ عِنْدَ الْعَصْرِ، فَتَوَضَّؤُوا وَهُمْ عِجَالٌ، فَانْتَهَيْنَا إِلَيْهِمْ وَأَعْقَابُهُمْ تَلُوحُ لَمْ يَمَسَّهَا الْمَاءُ فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «وَيْلٌ لِلْأَعْقَابِ مِنَ النَّارِ أَسْبِغُوا الْوُضُوءَ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 241]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amru ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji o sọ pe:
A ṣẹri pada pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati Makkah lọ si Madina titi ti a fi kan omi ni oju-ọna, awọn ikọ kan yara fun irun Asri, ti wọn si ṣe aluwala ni ẹni ti n kanju, ni a ba wa ba wọn ti awọn gigisẹ wọn han ti omi o si de ibẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Egbe ki o maa ba gbogbo gigisẹ (ti omi o de) ninu ina, ẹ ṣe aluwala yin daadaa».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 241]
Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe irin-ajo lati Makkah lọ si Madina ti awọn saabe rẹ si wa pẹlu rẹ, ni oju-ọna wọn wọ́n rí omi, ti apakan ninu awọn saabe sì yara ṣe aluwala fún irun Asri debi pe gbigbẹ awọn gigisẹ fun omi han si kedere, ni Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- wa sọ pe: Iya ati iparun ninu ina n bẹ fun gbogbo olùṣe aseeto nibi fifọ gigisẹ nibi aluwala, o si tun pa wọn lasẹ ki wọn maa ṣe aluwala ni pipe.