Ìsọ̀rí:
+ -


____

[] - []
المزيــد ...

Lati ọdọ baba Abdul Rahman ọmọ Umar ọmọ Alkhattob kí Ọlọhun yọnu sí o s'ọpe: mogbọ tí òjíṣẹ Ọlọhun kí ikẹ àti ọlá Rẹ má bà nsọ. pe :
«Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún: Ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ẹru Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati imaa gbe irun duro, ati imaa yọ zakah, ati imaa gbero ile Oluwa, ati gbigba aawẹ Ramadan».

[O ni alaafia] - [رواه البخاري ومسلم] - [الأربعون النووية - 3]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi Isilaamu jọ ile kan ti wọn mọ daadaa pẹlu origun maarun ti o gbe ile naa duro, ti awọn iwa Isilaamu ti o sẹku jẹ pipari ile naa. Akọkọ awọn origun yii ni: Ijẹrii mejeeji; ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe origun kan ni mejeeji; ti ọkan o lee ja kuro lara ìkejì, ẹru o sọ mejeeji ni ẹni ti n fi ijẹ ọkan ṣoṣo Ọlọhun ati lilẹtọọ Rẹ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo laisi ẹlòmíràn yatọ si i rinlẹ, ti yio si maa ṣiṣẹ tọ awọn nkan ti o n tọka si, ki o si tun gba iransẹ Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gbọ ni ẹni ti yio maa tẹle e. Origun keji ni: Gbigbe irun duro, oun naa ni awọn irun ọranyan marun-un ni ojumọ kan ati oru kan: Alufajari, ati Àílà, ati Alaasari, ati Magribi, ati Ishai, pẹlu awọn majẹmu wọn ati awọn origun wọn ati awọn ọranyan wọn. Origun kẹta ni: Yiyọ zakah ọranyan, oun naa ni ijọsin owo ti o jẹ dandan nibi gbogbo dukia ti o ba ti to odiwọn ti wọn fi aala si ninu shariah, ti wọn o fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i. Origun kẹrin ni: Hajji, oun naa ni gbigbero Makkah lati gbe awọn iṣẹ ìjọsìn duro, ni ti jijọsin fun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn. Origun karun-un ni: Aawẹ Ramadan, oun naa ni kikoraro nibi jijẹ ati mimu ati nkan ti o yatọ si mejeeji ninu awọn nkan ti o le ba aawẹ jẹ pẹlu aniyan jijọsin fun Ọlọhun, lati igba ti alufajari ba ti yọ titi ti oorun yio fi wọ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Sisopapọ ijẹrii mejeeji, nitori naa ọkan ninu mejeeji o lee ni alaafia ayaafi pẹlu ikeji; fun idi eyi ni wọn fi ṣe mejeeji ni origun kan.
  2. Ijẹrii mejeeji ni ipilẹ ẹsin, nitori naa wọn o nii tẹwọ gba ọrọ kan abi iṣẹ kan ayaafi pẹlu mejeeji.
Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية الأكانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية الخميرية الماراثية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún