عَنِ ابنِ مَسعُودٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«لَا يَحِلُّ دَمُ امْرِئٍ مُسْلِمٍ إِلَّا بِإِحْدَى ثَلَاثٍ: الثَّيِّبُ الزَّانِي، وَالنَّفْسُ بِالنَّفْسِ، وَالتَّارِكُ لِدِينِهِ المُفَارِقُ لِلْجَمَاعَةِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1676]
المزيــد ...
Láti ọdọ Ibnu Mas'ud kí Ọlọhun yọnu si; o s'ọpé: Òjíṣẹ́ Ọlọhun kí ikẹ àti ọla Ọlọhun máa ba a s'ọpe:
«kò lẹtọ láti ta ẹjẹ musulumi kankan silẹ ayaafi pẹlu ọkan nínú nkan mẹta: Adelebọ tàbí Abilekọ l'óbìnrin tàbí l'ọkunrin tí o ba se zina, ati ẹmi kan tí o pa ẹmi keji lai l'ẹtọ, àti ẹni tí o fi ẹṣin ṣílẹ tí o si yapa kuro ninu awujọ (awọn musulumi)".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1676]
Annabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ o máa ba a- ṣe alaye pé eewọ ni lati ta ẹjẹ musulumi silẹ, àyàfi tí o ba ṣe ọkan nínú awọn nkan mẹta (wọnyi): Alakọkọ: ẹni tí o ba ṣe àgbèrè (zina), tí o si jasi pe o ti ṣe ìgbeyàwó l'ọna tí o lalaafia, nigbanaa o tọ kí a o sọ l'oko pa (titi ti ẹmi o fi bọ lara rẹ). Ẹlẹẹkeji: ẹnikẹni ti o ba maama pa ẹmi kan (ti a se l'eewọ lati pa) laisi ẹtọ, a o pa oun naa di pẹlu awọn majẹmu (ati ofin) ti o ro papọ mọ. Ẹlẹkẹta: ẹni tí o ba yapa kúrò láàrin awujọ awọn musulumi, bóyá nipa fífi ẹṣin Islam silẹ nipasẹ (Ridda), tabi ẹni tí o nya pá l'ọtọ lai ṣe (Ridda) nipasẹ fífi apakan (ofin Islam) silẹ, gẹgẹ bi awọn obilẹjẹ ènìyàn, àti awọn adigun jàle, ati awọn olujagun nínú àwọn Khawaarij àti awọn miran.