عن عمر بن الخطاب رضي الله عنه قال: إنه سمع نبي الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«لَو أَنَّكُمْ تَتَوَكَّلُونَ عَلَى اللهِ حَقَّ تَوَكُّلِهِ، لَرَزَقَكُمْ كَمَا يَرْزُقُ الطَّيْرَ، تَغْدُو خِمَاصًا وَتَرُوحُ بِطَانًا».
[صحيح] - [رواه الترمذي وابن ماجه وأحمد] - [مسند أحمد: 205]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Oun gbọ ti Anọbi Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Ti o ba jẹ pe ẹ n gbẹkẹle Ọlọhun gẹgẹ bi o ti yẹ ki ẹ gbẹkẹle E ni, Oun iba pese fun yin gẹ́gẹ́ bí O ti pese fun awọn ẹyẹ, ti wọn maa jade ni owurọ pẹlu ebi, ti wọn si maa pada ni irọlẹ ti wọn si ti yó.”
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 205]
Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, gba wa niyanju lati gbẹkẹle Ọlọhun lati mu anfaani wa ati lati yago fun ipalara ninu ọ̀rọ̀ aye ati ẹsin. Ko si ẹni ti o le fun èèyàn ni nǹkan tabi fi nǹkan dun èèyàn, tabi ko inira ba èèyàn tabi ṣe èèyàn ni anfaani ayafi Ọlọhun Ọ̀gá-ògo, Ki a si ṣe awọn okunfa ti o maa mu anfaani wa, ti o si maa dènà ipalara, pẹlu gbigbẹkẹle Ọlọhun ti òdodo, ti a ba ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọhun maa pese fun wa bi O ti n pese fun awọn ẹyẹ ti wọn n jade ni owurọ pẹ̀lú ebi. Lẹ́yìn naa wọn maa pada ni irọlẹ ti ikun wọn si ti kún, ati pe iṣe ti ẹyẹ yii jẹ ọkan ninu awọn ọ̀nà igbiyanju lati wa jíjẹ-mímu, laisi igbẹkẹle asán ati ìmẹ́lẹ́.