عَنْ عَائِشَةَ رضي الله عنها قَالَتْ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ أَحْدَثَ فِي أَمْرِنَا هَذَا مَا لَيْسَ فِيهِ فَهُوَ رَدٌّ» متفق عليه.
ولمسلم: «مَنْ عَمِلَ عَمَلًا لَيْسَ عَلَيْهِ أَمْرُنَا فَهُوَ رَدٌّ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2697]
المزيــد ...
Lati ọdọ 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu alamọri wa yii ninu nnkan ti ko si nibẹ, wọn maa da a pada ni" Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa. O n bẹ fun Muslim pé: "Ẹni ti o ba ṣe iṣẹ kan ti ko si àṣẹ wa nibẹ, wọn maa da a pada ni"
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2697]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu ẹsin tabi ti o ba ṣe iṣẹ kan ti ẹri kankan ko da le e lori ninu Kuraani ati sunnah, wọn maa da a pada fun ẹni ti o ba ṣe e, ko nii jẹ ìtẹ́wọ́gbà lọdọ Ọlọhun.