عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«مَنْ دَعَا إِلَى هُدًى كَانَ لَهُ مِنَ الْأَجْرِ مِثْلُ أُجُورِ مَنْ تَبِعَهُ، لَا يَنْقُصُ ذَلِكَ مِنْ أُجُورِهِمْ شَيْئًا، وَمَنْ دَعَا إِلَى ضَلَالَةٍ كَانَ عَلَيْهِ مِنَ الْإِثْمِ مِثْلُ آثَامِ مَنْ تَبِعَهُ، لَا يَنْقُصُ ذَلِكَ مِنْ آثَامِهِمْ شَيْئًا».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2674]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn, ati pe ẹni ti o ba pepe lọ si ibi anu, iru awọn ẹṣẹ ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹṣẹ, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2674]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o fi eniyan mọna ti o si tọka ti o si ṣe awọn eniyan lojukokoro lọ sibi oju ọna kan ti ododo ati daadaa n bẹ nibẹ pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹsan ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu ẹsan olutẹle náà. Ati pe ẹni ti o ba dari ti o si tọka awọn eniyan lọ sibi oju ọna ibajẹ ati aburu, ti ẹṣẹ ati àṣìṣe tabi ti àlámọ̀rí ti ko lẹtọọ n bẹ nibẹ, pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹṣẹ ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn.