عَنْ سَلَمَةَ بْنِ الْأَكْوَعِ رضي الله عنه:
أَنَّ رَجُلًا أَكَلَ عِنْدَ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ بِشِمَالِهِ، فَقَالَ: «كُلْ بِيَمِينِكَ»، قَالَ: لَا أَسْتَطِيعُ، قَالَ: «لَا اسْتَطَعْتَ»، مَا مَنَعَهُ إِلَّا الْكِبْرُ، قَالَ: فَمَا رَفَعَهَا إِلَى فِيهِ.
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2021]
المزيــد ...
Lati ọdọ Salamah ọmọ Al-hakwa'u- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa", nnkan ko kọdi rẹ afi igberaga, o sọ pe: Ko si lee gbe e si ẹnu rẹ mọ.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2021]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ri arakunrin kan ti o n jẹun pẹlu ọwọ rẹ osi, o wa pa a láṣẹ lati jẹun pẹlu ọwọ rẹ ọtun, Arakunrin naa wa da a lohun ni ti igberaga ati irọ pe oun ko ni ikapa! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹbi le e pe ki wọn ṣe jijẹ pẹlu ọwọ ọtun leewọ fun un, Ọlọhun ba gba adura Anabi Rẹ pe ki ọwọ ọtun rẹ rọ, ko si lee gbe e si ẹnu rẹ lẹyin ìyẹn pẹlu oúnjẹ tabi nǹkan mimu.