+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«صَلَاةُ الرَّجُلِ فِي جَمَاعَةٍ تَزِيدُ عَلَى صَلَاتِهِ فِي بَيْتِهِ وَصَلَاتِهِ فِي سُوقِهِ بِضْعًا وَعِشْرِينَ دَرَجَةً، وَذَلِكَ أَنَّ أَحَدَهُمْ إِذَا تَوَضَّأَ فَأَحْسَنَ الْوُضُوءَ، ثُمَّ أَتَى الْمَسْجِدَ لَا يَنْهَزُهُ إِلَّا الصَّلَاةُ، لَا يُرِيدُ إِلَّا الصَّلَاةَ، فَلَمْ يَخْطُ خَطْوَةً إِلَّا رُفِعَ لَهُ بِهَا دَرَجَةٌ، وَحُطَّ عَنْهُ بِهَا خَطِيئَةٌ، حَتَّى يَدْخُلَ الْمَسْجِدَ، فَإِذَا دَخَلَ الْمَسْجِدَ كَانَ فِي الصَّلَاةِ مَا كَانَتِ الصَّلَاةُ هِيَ تَحْبِسُهُ، وَالْمَلَائِكَةُ يُصَلُّونَ عَلَى أَحَدِكُمْ مَا دَامَ فِي مَجْلِسِهِ الَّذِي صَلَّى فِيهِ، يَقُولُونَ: اللهُمَّ ارْحَمْهُ، اللهُمَّ اغْفِرْ لَهُ، اللهُمَّ تُبْ عَلَيْهِ، مَا لَمْ يُؤْذِ فِيهِ، مَا لَمْ يُحْدِثْ فِيهِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 649]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
“Irun ọkunrin kan pẹ̀lú janmọọn ju irun rẹ nile lọ ati Irun rẹ ni ọja lọ pẹlu ipò ogún lé ní nǹkan kan. nitori pe ti ẹnìkan ninu wọn ba ṣe aluwala daadaa, lẹ́yìn naa o wa lọ sí mọ́sálásí, ko si nkankan ti o gbe e dide ayafi irun, ko si gbero nǹkan kan ayafi irun, nitori naa ko nii gbe ẹsẹ kan àyàfi ki Ọlọhun fi ṣe agbega fun un, ati ki O fi pa asiṣe rẹ rẹ́, titi ti yio fi wọ masalasi. Ti o ba ti wa wọ mọ́sálásí, o ti wa lori irun lópin igba ti o ba jẹ pe irun ni o n da a dúró, àwọn Malaika si ma maa ṣe adura fun ẹni kọọkan ninu yin ni iwọn igba ti o ba ṣi wa lori ijokoo ti o ti kirun, wọn maa sọ pe: Ọlọhun, ṣãnu fun un, Ọlọrun, dari jin in, Ọlọrun, gba ironupiwada rẹ, ni iwọn igba ti ko ba ti ṣe ipalara nibẹ, ti ko si ṣe ẹgbin nibẹ".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 649]

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- sọ fun wa wí pé ti musulumi ba ki Irun ni janmọọn, Irun rẹ ni ọla ju Irun rẹ ni ile tabi ni ọja lọ ni ọ̀nà igba ti o le ni ogún. Lẹ́yìn naa ni o sọ okùnfà ìyẹn: Oun naa ni pé ti ọkùnrin kan ba ṣe aluwala ti o si pari aluwala naa ti o si ṣe e daadaa, ti o wa jade lọ si mọ́sálásí, ti ko si si ohun ti o gbe e jade ayafi ìrun, ko nii gbe ẹsẹ kan àyàfi ki wọn ṣe ipo to ga ati aaye to ga fun un, ki wọn si tun fi pa àṣìṣe rẹ rẹ. Ti eniyan ba wọ inu mọṣalaṣi ti o si jokoo ti o n duro fun Irun, yìo gba ẹ̀san Irun lopin ìgbà tí ó bá ṣi n retí irun, àwọn Malaika a maa se adua fun un, ni igba ti o ba wa ni ori ìjókòó ti o ti kirun, wọn maa sọ pe: Ọlọhun, dárí jin in, Ọlọhun, ṣãnu fun un, Ọlọrun, gba ironupiwada rẹ,” , lopin ìgbà tí aluwala rẹ ko ba i tii bajẹ, ti ko si ṣe ipalara fun eniyan tabi awọn angẹli.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Irun enikan nínú ilé tàbí ní ọjà, ó ni alaafia; ṣùgbọ́n o maa gba ẹṣẹ fun pe o gbe irun janmọọn ju silẹ láìní àwíjàre kankan.
  2. Irun janmọọn nínú mọ́sálásí ju irun adaki lọ pẹlu ẹsan mẹẹdọgbọn, tabi mẹrindinlọgbọn, tabi mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
  3. Ọkan ninu awọn iṣẹ ti awọn angẹli ni adua siṣe fun awọn onigbagbọ.
  4. Ọla lilọ sí mọ́sálásí ni ẹni tí o ni aluwala.