عن أبي هريرة رضي الله عنه قال:
أَتَى النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ رَجُلٌ أَعْمَى، فَقَالَ: يَا رَسُولَ اللهِ، إِنَّهُ لَيْسَ لِي قَائِدٌ يَقُودُنِي إِلَى الْمَسْجِدِ، فَسَأَلَ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ أَنْ يُرَخِّصَ لَهُ فَيُصَلِّيَ فِي بَيْتِهِ، فَرَخَّصَ لَهُ، فَلَمَّا وَلَّى دَعَاهُ، فَقَالَ: «هَلْ تَسْمَعُ النِّدَاءَ بِالصَّلَاةِ؟» فَقَالَ: نَعَمْ، قَالَ: «فَأَجِبْ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 653]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe:
Arakunrin afọju kan wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ko si ẹni ti yio fa mi wa si mọṣalaṣi, ni o wa bi Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere ki o ṣe ẹdẹ fun un ki o maa kirun ni inu ile rẹ, ni o wa ṣe ẹdẹ fun un, nigba ti o wa yi ẹyin pada, o pe e, o wa sọ fun un pe: «Njẹ o maa n gbọ ipe irun?» O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: «Ki o ya dahun».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 653]
Arakunrin afọju kan wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ko si lọdọ mi ẹni ti o le maa ran mi lọwọ ti yio si maa fa mi wa si mọṣalaṣi ni asiko awọn irun maraarun, o n wa lati ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ki o ṣe ẹdẹ fún un nibi gbigbe irun janmọọn ju silẹ, nigba naa ni o wa ṣe ẹdẹ fun un, nigba ti o wa yi ẹyin pada, o pe e, o wa sọ fun un pe: Njẹ o maa n gbọ ipe irun? O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: Ki o yaa jẹ ipe oluperun.