+ -

عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الْخُدْرِيِّ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِذَا شَكَّ أَحَدُكُمْ فِي صَلَاتِهِ، فَلَمْ يَدْرِ كَمْ صَلَّى ثَلَاثًا أَمْ أَرْبَعًا، فَلْيَطْرَحِ الشَّكَّ، وَلْيَبْنِ عَلَى مَا اسْتَيْقَنَ، ثُمَّ يَسْجُدُ سَجْدَتَيْنِ قَبْلَ أَنْ يُسَلِّمَ، فَإِنْ كَانَ صَلَّى خَمْسًا شَفَعْنَ لَهُ صَلَاتَهُ، وَإِنْ كَانَ صَلَّى إِتْمَامًا لِأَرْبَعٍ كَانَتَا تَرْغِيمًا لِلشَّيْطَانِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 571]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe iyemeji nibi irun rẹ, ti ko si mọ iye ti o ki boya mẹta ni tabi mẹrin, ki o yaa ju iyemeji naa nù, ki o mọ irun rẹ lori nnkan ti o da a loju, lẹyin naa, o maa forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹẹmeji ṣíwájú ki o to salamọ, ti o ba ki marun-un wọn maa ṣe irun rẹ ni nǹkan ti eéjì le pin fun un, ti o ba ki i lati pe mẹrin, mejeeji maa jẹ iyẹpẹrẹ fún èṣù".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 571]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju olukirun ti o ba ṣe iyemeji nibi irun rẹ ti ko mọ iye ti o ki, boya mẹta ni tabi mẹrin? Ki o gbe onka ti o lekun ti o n ṣe iyemeji nipa rẹ jinna ki o ma lo o: mẹta ni o da a loju, o maa ki rakah kẹrin, lẹyin naa o maa forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹẹmeji ṣíwájú ki o to salamọ.
Ti o ba ṣe pe nnkan ti o ki jẹ mẹrin ni òtítọ́; o maa di marun-un pẹlu alekun rakah kan, ti iforikanlẹ mejeeji ti igbagbe maa jẹ ijirọ fun rakah kan, onka naa maa jẹ nǹkan ti eéjì le pin ko nii jẹ nǹkan tí eeji ko le pin: Ti o ba wa ki mẹrin pẹlu rakah ti o lekun; o maa jẹ pe o ti ṣe nnkan ti o jẹ dandan fun un laisi alekun tabi adinku.
Iforikanlẹ igbagbe mejeeji jẹ iyẹpẹrẹ fún shaytaan ati ile e jina, ati lile e jina si erongba rẹ; torí pé o ti da irun rẹ ru mọ ọn l'oju, ti o si tun fẹ ba a jẹ, ati pe irun ọmọ Anabi Ādam pe nígbà tí o ba ti tẹle aṣẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pẹlu iforikanlẹ eleyii ti èṣù yapa nitori rẹ, nígbà tí o kọ lati tẹle àṣẹ Ọlọhun pẹlu fifi orikanlẹ fun Ādam.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ti ẹni ti n kirun ba ṣe iyemeji ninu irun rẹ ti ikankan ninu alamọri mejeeji o si leke ni ọdọ rẹ, dajudaju ni igba naa yio ti iyemeji danu ti yio si ṣe amulo amọdaju, oun naa ni eyi ti o kere ju, nitori naa yio pe irun rẹ yio si fi ori kanlẹ fun igbagbe ṣaaju ki o to salamọ lẹyin naa yio wa salamọ.
  2. Iforikanlẹ mejeeji yii jẹ ọna lati tun irun ṣe, o tun jẹ dida èṣù pada ni ẹni yẹpẹrẹ ti wọn gbe jìnnà si erongba rẹ̀.
  3. Iyemeji ti o wa ninu hadīth yii oun ni iyemeji laisi pe ọkan tẹsunwọn ju ọkan lọ, ti a ba wa ri èrò ti o tẹsunwọn, a maa lo o.
  4. Ṣiṣenilojukokoro lori gbigbe ogun ti royiroyi ati titi i danu pẹlu titẹle aṣẹ ofin (Ọlọhun).
Àlékún