عن تَميم الداري رضي الله عنه، قال: سمعتُ رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«لَيَبْلُغَنَّ هَذَا الأَمْرُ مَا بَلَغَ اللَّيْلُ وَالنَّهَارُ، وَلَا يَتْرُكُ اللهُ بَيْتَ مَدَرٍ وَلَا وَبَرٍ إِلَّا أَدْخَلَهُ اللهُ هَذَا الدِّينَ، بِعِزِّ عَزِيزٍ أَوْ بِذُلِّ ذَلِيلٍ، عِزًّا يُعِزُّ اللهُ بِهِ الإِسْلَامَ، وَذُلًّا يُذِلُّ اللهُ بِهِ الكُفْرَ» وَكَانَ تَمِيمٌ الدَّارِيُّ يَقُولُ: قَدْ عَرَفْتُ ذَلِكَ فِي أَهْلِ بَيْتِي، لَقَدْ أَصَابَ مَنْ أَسْلَمَ مِنْهُمُ الْخَيْرُ وَالشَّرَفُ وَالْعِزُّ، وَلَقَدْ أَصَابَ مَنْ كَانَ مِنْهُمْ كَافِرًا الذُّلُّ وَالصَّغَارُ وَالْجِزْيَةُ.
[صحيح] - [رواه أحمد] - [مسند أحمد: 16957]
المزيــد ...
Lati ọdọ Tamīm ad-Dāriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe:
«O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ, pẹlu iyi abiyi tabi iyẹpẹrẹ ẹni yẹpẹrẹ, ni iyi kan ti Ọlọhun maa fi fun Isilaamu niyi ati iyẹpẹrẹ kan ti Ọlọhun maa fi yẹpẹrẹ iṣe keferi» Tamīm ad-Dāriy maa n sọ pe: Mo mọ ìyẹn ni ara awọn ara-ile mi, oore ati iyì ti ṣẹlẹ̀ fun ẹni tí o gba Isilaamu nínú wọn, ti iyẹpẹrẹ ati sísan isakọlẹ si ṣẹlẹ fun ẹni ti o jẹ keferi ninu wọn.
[O ni alaafia] - [Ahmad ni o gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 16957]
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ẹsin yìí maa pada kari gbogbo àwọn ipin ilẹ̀, èyíkéyìí aaye ti oru ati ọsan de ni ẹsin yìí maa pada de, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii fi ile kan sílẹ̀ láéláé ni awọn ilu ati awọn oko tabi ni aṣalẹ afi ki O mu ẹsin yii wọnu rẹ, Ẹni ti o ba gba ẹsin yii ti o si ni igbagbọ ninu rẹ dajudaju o maa di abiyi pẹlu iyi Isilaamu, Ẹni ti o ba kọ ọ ti o saigbagbọ pẹlu rẹ o maa di ẹni yẹpẹrẹ ati eni ẹtẹ.
Lẹyin naa, saabe ti o n jẹ Tamiim Ad-Daari- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe oun mọ ìyẹn ti ojiṣẹ Ọlọhun sọ lara awọn ara ile rẹ, torí pé ẹni ti o gba Isilaamu ninu wọn ri oore ati iyi, ẹni ti o ṣe aigbagbọ ninu wọn si ri iyẹpẹrẹ ati ẹtẹ pẹlu owo ti o tun n san fun awọn Mùsùlùmí.