+ -

عن عبد الله بن مسعود رضي الله عنه قال:
عَلَّمَنَا رَسُوْلُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ خُطْبَةَ الحَاجَةِ: إِنَّ الحَمْدَ للهِ، نَسْتَعِيْنُهُ وَنَسْتَغْفِرُهُ، وَنَعُوْذُ بِهِ مِنْ شُرُوْرِ أَنْفُسِنَا، مَنْ يَهْدِ اللهُ فَلَا مُضِلَّ لَهُ، وَمَنْ يُضْلِلْ فَلَا هَادِيَ لَهُ، وَأَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا الله، وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُوْلُهُ، {يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالًا كَثِيرًا وَنِسَاءً وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي تَسَاءَلُونَ بِهِ والأرحام إن الله كان عليكم رقيبا} [النساء: 1]، {يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ حَقَّ تُقَاتِهِ وَلَا تَمُوتُنَّ إِلَّا وَأَنْتُمْ مُسْلِمُونَ} [آل عمران: 102]، {يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَقُولُوا قَوْلًا سَدِيدًا (70) يُصْلِحْ لَكُمْ أَعْمَالَكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَمَنْ يُطِعِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَقَدْ فَازَ فَوْزًا عَظِيمًا} [الأحزاب:70 - 71].

[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وابن ماجه والنسائي وأحمد] - [سنن أبي داود: 2118]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wa ni khutubal haajah: Innal hamda lillah, nasta’eenuhu wa nastagfiruhu, wa na’uudhu bihi min shuruuri anfusinaa, man yahdii llohu falaa mudilla lahu, wa man yudlil fa laa haadiya lahu, wa ash-hadu an laa ilaaha illallohu, wa ash-hadu anna Muhammadan ‘abduhu wa rosuuluhu, (Yaaa ayyuhan naasut taqoo Rabbakumul lazee khalaqakum min nafsinw waahidatinw wa khalaqa minhaa zawjahaa wa bas sa minhumaa rijaalan kaseeranw wa nisaaa’aa; wattaqul laahallazee tasaaa ‘aloona bihee wal arhaam; innal laaha kaana ‘alaikum Raqeeba) (An-Nisa: 1), (Yaaa ayyuhal lazeena aamanut taqul laaha haqqa tuqaatihee wa laa tamootunna illaa wa antum muslimoon) (Aal-Imran: 102), (Yaaa ayyuhal lazeena aamanut taqul laaha wa qooloo qawlan sadeedaa(70) Yuslih lakum a’maalakum wa yaghfir lakum zunoobakum; wa mai yuti’il laaha wa Rasoolahoo faqad faaza fawzan ‘azeemaa) (Al-Ahzab: 70-71).

[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Nasaa'iy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 2118]

Àlàyé

Ọmọ Mas’ud - ki Ọlọhun yọnu si i - n sọ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wọn ni khutubal haajah, oun ni wọn maa n sọ nibi ìbẹ̀rẹ̀ ọrọ nibi khutubah ati níwájú bukaata wọn, gẹgẹ bii khutubah igbeyawo ati khutubah irun Jimoh ati eyi ti o yatọ si wọn, Ati pe khutubah yii ko awọn ìtumọ̀ ti o tobi sinu bii alaye pe Ọlọhun lẹtọọ si gbogbo awọn iran ọpẹ, ati wiwa iranlọwọ lọdọ Rẹ ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati bibo awọn ẹṣẹ ati mimu oju kuro nibẹ, ati sisadi I kuro nibi gbogbo aburu, ati awọn aburu ẹmi ati eyi ti o yatọ si wọn.
Lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju imọna ọwọ Ọlọhun ni o wa, ẹni ti O ba fi mọna ko si oluṣini-lọna kan fun un, ẹni ti O ba ṣi lọna ko si atọnisọna kan fun un.
Lẹyin naa o darukọ ijẹrii imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo pe oun ni pe ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, ati pe ijẹrii iṣẹ́-rírán ni pe dajudaju Muhammad jẹ ẹrusin Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ.
O pari khutubah yii pẹlu awọn aayah mẹta ti wọn ko àṣẹ pẹlu ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sinu pẹlu ṣiṣe awọn àṣẹ Rẹ ati jijina si awọn nǹkan ti Ó kọ̀ lati fi wa oju rere Ọlọhun, ati pe dajudaju ẹsan ẹni ti o ba ṣe iyẹn ni dídára awọn iṣẹ ati awọn ọrọ ati pipa awọn aburu rẹ ati aforijin awọn ẹṣẹ ati iṣẹmi ti o mọ ni aye ati erenjẹ pẹlu alujanna ni ọjọ igbedide.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe bibẹrẹ awọn khutubah igbeyawo ati ti irun jimọh ati eyi ti o yatọ si wọn pẹlu khutubah yii ni nnkan ti a fẹ.
  2. Khutubah lẹtọọ lati ko ọpẹ sinu ati ijẹrii mejeeji ati awọn aayah Kuraani kan.
  3. Kikọ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n kọ́ àwọn saabe ni nnkan ti wọn bukaata si ninu ẹsin wọn.