عن عُقبة بن عامر الجُهني رضي الله عنه قال: قال رسولُ الله صلَّى الله عليه وسلم:
«الجاهِرُ بالقرآن كالجاهِرِ بالصَّدَقَةِ، والمُسِرُّ بالقرآن كالمُسِرِّ بالصَّدَقَة».

[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي والنسائي] - [سنن أبي داود: 1333]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Uqbah ọmọ Aamir Al-Juhaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”.

[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 1333]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ẹni ti ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni tí n kéde sàárà ṣíṣe, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni tí n fi sàárà pamọ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Kika Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ ni o ni ọlá jù, gẹgẹ bi fifi sàárà pamọ naa ṣe ní ọlá jù; tori imọkanga ti o wa nibẹ, ati ijinna si ṣekarimi ati motomoto, àyàfi tí bukaata tabi anfaani ba pepe lọ sibi ki a ka a sókè, gẹgẹ bii kikọ èèyàn ni Kuraani.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (65)