+ -

عَنْ أَبِي بَرْزَةَ الأَسْلَمِيِّ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«لَا تَزُولُ قَدَمَا عَبْدٍ يَوْمَ القِيَامَةِ حَتَّى يُسْأَلَ عَنْ عُمُرِهِ فِيمَا أَفْنَاهُ، وَعَنْ عِلْمِهِ فِيمَ فَعَلَ، وَعَنْ مَالِهِ مِنْ أَيْنَ اكْتَسَبَهُ وَفِيمَ أَنْفَقَهُ، وَعَنْ جِسْمِهِ فِيمَ أَبْلَاهُ».

[صحيح] - [رواه الترمذي] - [سنن الترمذي: 2417]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Barzata Al-aslamiy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si».

[O ni alaafia] - [Tirmiziy ni o gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2417]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹnikẹni ninu awọn eeyan ko nii tayọ aaye iṣiro iṣẹ ni ọjọ igbedide lọ si alijanna tabi ina titi ti wọn o fi bi i nipa awọn alamọri kan:
Alakọkọọ: Iṣẹmi rẹ nibo ni o pari rẹ sí?
Ẹlẹẹkeji: Imọ rẹ njẹ o wa a nitori ti Ọlọhun? Ati pe njẹ o fi ṣiṣẹ ṣe? Ati pe njẹ o mu un de ọdọ ẹni ti o lẹtọọ si i?
Ẹlẹẹkẹta: Dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ṣe nibi ẹtọ ni abi níbi eewọ? Ati pe nibo ni o na an si, ṣe ibi nkan ti o yọ Ọlọhun ninu ni abi ibi ti o bi I ninu?
Ẹlẹẹkẹrin: Ara rẹ ati agbara rẹ ati alaafia rẹ ati ọdọ rẹ nibo ni o lo o si?

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣeni ni ojukokoro lori lilo iṣẹmi s'ibi nkan ti yio yọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ninu.
  2. Awọn idẹra Ọlọhun pọ lori awọn ẹru, ati pe yio bi i leere nipa idẹra eleyii ti o wa ninu rẹ, nitori naa o jẹ dandan fun un ki o gbe awọn idẹra Ọlọhun sí ibi tí yio yọ Ọ ninu.